Àfihàn ìgbà tí Nàìjíríà sé àṣekágbá ìdíje Afcon, àmọ́ tó bọ́ mọ́ wọ́n lọ́wọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ní alẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kejì ọdún 2024 ni ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀, African Cup of Nations (AFCON) wá sópin bí orílẹ̀ èdè Ivory Coast ṣe gbo ewúro sójú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà pẹ̀lú góòlù méjì sí ẹyọ̀kan.
Super Eagles ló kọ́kọ́ ń léwájú nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà nígbà tí balógun ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Troost-Ekong mi àwọ̀n àwọn Erinlákátabú ti Ivory Coast.
Àmọ́ níṣe ni ọ̀rọ̀ bá ẹ̀yìn yọ nígbà tí Frank Kessie kọ́kọ́ fi orí sọ góòlù sáwọ̀n Nàìjíríà, tí Sebastien Haller náà sì tí fi òmíràn lé nígbà tó ku ìṣẹ̀jú mẹ́sàn-án kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà parí.
Ìdíje náà parí pẹ̀lú góòlù méjì sódo tí Nàìjíríà sì pàdánù láti gba ife ẹ̀yẹ náà fún ìgbà kẹrin lẹ́yìn tí wọ́n ti gbà á kẹ́yìn lọ́dún 2013.
Èyí ló ti ń fa awuyewuye láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Nàìjíríà ti kópa ní ìpele àṣekágbá AFCON ṣùgbọ́n tí wọn kò gbà á ju ẹ̀ẹmẹta lọ.
Ìgbà kẹjọ rèé tí Nàìjíríà yóò kópa níbi àṣekágbá ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ AFCON àmọ́ tí wọ́n fìdí rẹmi ní ìgbà márùn-ún.
Ní ọdún 1980, 1994 àti 2013 ni Nàìjíríà gba ife ẹ̀yẹ AFCON láti ìgbà tí wọ́n ti ń kópa nínú ìdíje náà.
Bákan náà ni wọ́n ti pàdánù rẹ̀ lọ́dún 1984, 1988, 1990, 2000 àti 2024 lẹ́yìn tí wọ́n dé abala àṣekágbá ìdíje ọ̀hún.
Ní ọdún 1963 ni Naijiria kópa nínú ìdíje AFCON fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà tí ìdíje náà ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1957.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlógún tí Naijiria ti ń kópa nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ náà ni wọ́n tó dé abala àṣekágbá rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lọ́dún 1980.
Nàìjíríà ni ó ṣe agbátẹrù ìdíje náà tí wọ́n sì gba ife ẹ̀yẹ ọ̀hún mọ́ orílẹ̀ èdè Algeria tí wọ́n jọ kojú ara wọn lọ́wọ́.
Orílẹ̀ èdè Morocco ni Naijiyria bá gbá ní abala tó kángun sí àṣekágbá kí wan tó pàdé Algeria ní abala tó kẹ́yìn nínú ìdíje ọ̀hún.
Segun Odegbami ló gbá góòlù mẹ́ta tí wọ́n fi na Algeria, tó sì gba àmì ẹ̀yẹ pé òun ló gbá bọ́ọ̀lù sínú àwọ̀nọ̀ jùlọ nínú ìdíje náà.
Ìjákulẹ̀ bẹ̀rẹ̀ fún Nàìjíríà lẹ́yìn tí wọ́n gba ife ẹ̀yẹ ọdún 1980 yìí tán nígbà tí wọ́n pàdé orílẹ̀ èdè Cameroon ní ipele àṣekágbá.
Orílẹ̀ èdè Ivory Coast ló gbàlejò AFCON lọ́dún 1984 tí Nàìjíríà sì móríbọ́ wọ ipele àṣekágbá níbi tí wọ́n ti kojú orílẹ̀ èdè Cameroon.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà ló kọ́kọ́ jẹ góòlù kan látọwọ́ Muda Lawal níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà lọ́dún lọ́hùn-ún, góòlù mẹ́ta ni Cameroon fi dá padà fún Nàìjíríà láti gba ife ẹ̀yẹ náà.
Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀ èdè méjéèjì yìí tún pàdé níbi àṣekágbá AFCON ní orílẹ̀ èdè Morocco lọ́dún 1988 tí Cameroon tún gba ife ẹ̀yẹ náà mọ́ Nàìjíríà lọ́wọ́.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá ọdún 1988 náà ní kọ́nú n kọ́họ kan nínú díẹ̀ nítorí adarí ayò, ọmọ orílẹ̀ èdè Mauritanian, Sarr tó darí ìdíje náà wọ́gilé góòlù tí Henry Nwosu kọ́kọ́ jẹ.
Àtúnwò ìdíje náà padà fi hàn pé góòlù náà jẹ àmọ́ ẹ̀pa ò bóró mọ́ fún Nàìjíríà lẹ́yìn tí wọ́n ti fọn fèrè pé Cameroon ló jáwé olúborí ìdíje náà pllú góòlù kan sí òdo.
Ọdún 1994 ni ọmọ elépo Nàìjíríà tún ìgò wọn fọ̀ nígbà tí wọ́n gba ife ẹ̀yẹ náà fún ìgbà kejì lẹ́yìn tí wọ́n na orílẹ̀ èdè Zambia níbi àṣekágbá náà pẹ̀lú góòlù méjì sí ẹyọ̀kan.
Ìgbà ọ̀tun lágbo eré bọ́ọ̀lù ni ọdún 1994 jẹ́ fún Nàìjíríà nítorí ọdún yìí gan ni wọ́n kọ́kọ́ kópa níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé fún ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n sì tún móríbọ́ kúrò ní abala àkọ́kọ́ ìdíje náà.
Lẹ́yìn tí Nàìjíríà gba ìdíje AFCON 1994 tán ni gbogbo nǹkan tún dá gbáhú fún wọn bí wọ́n kò ṣe kópa nínú ìdíje AFCON tọdún 1996 tí South Africa ṣe agbétẹrù rẹ̀ àti ọdún 1998 tí Burkina Faso gbàlejò nítorí ipa tí ìròyìn ní ìjọba tó wà lóde nígbà náà kó lórí ìdíje náà ṣáájú ìdíje 1996
Nígbà tí Nàìjíríà ma padà sórí pápá lọ́dún 2000, wọ́n ri dájú pé àwọn tún dé abala àṣekágbá bákan náà àmọ́ tí Cameroon tún já wọn kulẹ̀ láti tún gba ife ẹ̀yẹ náà.
Cameroon gan ló gba àlejò ìdíje yìí lọ́dún 2000 yìí tí Nàìjíríà sì fi gbogbo ẹ̀mí wọn gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọ̀hún tó fi parí pẹ̀lú góòlù méjì méjì.
Pẹnáritì ló parí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà àmọ́ Super Eagles pàdánù láti gba ife ẹ̀yẹ ọ̀hún látàrí bí Kanu Nwankwo àti Victor Ikpeba kò gba bọ́ọ̀lù wọn sínú àwọ̀n.
Èyí túmọ̀ sí pé orílẹ̀ èdè Cameroon ni Nàìjíríà fìdí rẹmi sí lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹmẹta nínú ìgbà márùn-ún tí wọ́n pàdánù àṣekágbá ìdíje AFCON.
Ọdún 2013 ni Nàìjíríà tún móríbọ́ wọ ipele àṣekágbá ìdíje AFCON nígbà tí South Africa tún gbàlejò ìdíje náà.
Burkina Faso ni Nàìjíríà bá wàákò tí wọ́n sì nà wọ́n pẹ̀lú góòlù kan sí òdo èyí tí Sunday Mba jẹ fún Super Eagles.
Stephen Keshi, tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles lásìkò tí Nàìjíríà gba ife ẹ̀yẹ AFCON ọdún 1994 ni akọ́nimọ̀ọ́gbá tó gba ife ẹ̀yẹ náà fún Nàìjíríà lọ́dún 2013.
Ọdún mọ́kànlá lẹ́yìn tí Nàìjíríà gba ife ẹ̀yẹ AFCON fún ìgbà kẹta pẹ̀lú ìrètí pé wọn yóò gba ìkẹrin ni orílẹ̀ èdè Ivory Coast kò jẹ́ kí àlá wọn wá sí ìmúṣẹ lọ̀dún 2024.
Ivory Coast tó gbàlejò ìdíje náà ló gba ife ẹ̀yẹ ọ̀hún pẹ̀lú góòlù méjì sí ẹyọ̀kan.