Àsekágbá bọ́ọ̀lù Super Eagle : Ọ̀rọ̀ bí ìmò̩ràn fún àwọn ọmọ Naijiria tí wọn bà ní ẹ̀jẹ̀-ríru.

Àsekágbá bọ́ọ̀lù Super Eagle : Ọ̀rọ̀ bí ìmò̩ràn fún àwọn ọmọ Naijiria tí wọn bà ní ẹ̀jẹ̀-ríru.

Gbọ́láhàn Quseem

Kọmiṣanna tẹlẹ fun eto igbokegbodo ọkọ ati iṣẹ ode nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Rẹmi Ọmọwaiye, ti rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ọmọ Naijiria ti wọn ni aisan ẹjẹ-riru lati ma ṣe wo aṣekagbaa bọọlu AFCON ti yoo waye laarin ikọ agbabọọlu orileede Naijiria ati ti orileede Cote D’ivoire, lọjọ Aiku, Sannde to n bọ yii.
Eleyii ko ṣẹyin bi iroyin ṣe n lọ kaakiri nipa awọn eeyan ti wọn gbẹmi-in mi lẹyin idije to kangun si aṣekagba to waye laarin Super Eagles ati Bafana Bafana, ti orileede South Africa, l’Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu Keji, ọdun yii.
Bi ọkunrin oloṣelu kan, Dokita Cairo, ṣe ku nipinlẹ Delta, naa ni ọkunrin oniṣowo kan to jẹ ọmọ orileede Naijiria ku lorileede Cote D’ivoire. Bakan naa ni agunbanirọ kan to n sinru ilu ni Kaduna gbẹmi mi, ọrọ naa ko si yọ igbakeji akọwe Poli Kwara silẹ.
Iku gbogbo wọn ni awọn dokita oyinbo lọdii rẹ mọ bi aya wọn ṣe ja ju lasiko ti ere bọọlu naa n lọ lọwọ pẹlu ifunpa giga ti wọn ti ni tẹlẹ.
Latari idi eyi, Ọnarebu Rẹmi Ọmọwaiye sọ pe ohun to ṣẹlẹ lọjọ Wẹsidee yẹn ko tun gbọdọ ṣẹlẹ lonii nibikibi, idi niyi ti onikaluku fi gbọdọ mọ iwọn ara rẹ.
O ni ṣe loun gan-an bẹrẹ si i gbọn latinu, lasiko ti rẹfiri sọ pe ki awọn Bafana Bafana gba bọọlu goli-wo-mi-n-gba-a sinu awọn (net) Super Eagles lọjọ naa.
Ọmọwaiye sọ siwaju pe dipo ki awọn ti wọn ni ẹjẹ-riru wo bọọlu ọjọ Sannde yii, ṣe ni ki wọn fara balẹ wo atungba rẹ lẹyin ti wọn ba ti gbọ abajade ere bọọlu naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here