Amẹ́ríkà ṣetán àti ta bàlúù ọmọogun fún Nàìjíríà

Amẹ́ríkà ṣetán àti ta bàlúù ọmọogun fún Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Abàsíbíòwú ẹlikópítà iléeṣẹ́ ológun òfurufú ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti gbà láti ta àwọn nǹkan ìjà ológun fún Nàíjíríà kí wọ́n báa lè fi kojú àwọn jàndùkú agbébọn àti ikọ̀ Boko Haram.

Ọdún 2022 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìdúnàdúrà lórí nǹkan ìjà ológun yí ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ilé aṣòfin Amẹ́ríkà kan tó ní ó yẹ kí Nàíjíríà kájú òṣùnwọ̀n kọ̀ọ̀kan tí wọ́n là kalẹ̀ kí èyí tó lè wáyé.

Bóti lẹ̀ jẹ́ wí pé Nàíjíríà ti gbé iṣẹ́ àgbàṣe ríra nǹkan ìjà ológun mìí síta ṣáájú àsìkò yí, eléyìí ni ó pọ̀ jùlọ nínú àkọsílẹ ìdòwòpọ̀ Nàíjíríà àti Amẹ́ríkà lórí ọ̀rọ̀ nǹkan ìjà ológun.

Iye nǹkan ìjà ológun tí wọ́n fẹ́ tà fún Nàíjíríà lásìkò yí la gbọ́ pé ó jẹ́ bílíọ̀nù dọ́là kan.

Nínú àwọn nǹkan ìjà ológun yí la ti rí àwọn bàálù abàsíbíòwú táa mọ̀ sí ẹlikọ́ptà AH-1Z méjìlá àti àwọn ẹ̀rọ̀ kọ̀mpútà méjìlélọ́gbọ̀n láti ọ̀dọ̀ Northrop Grumman.

Àtẹ̀jáde tó fìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ̀ ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ yí jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì láti túnbọ̀ fagbára fún Nàíjíríà nípa kíkojú àwọn ìpèníjà ààbò.

Ìpèníjà ààbò Nàíjíríà táa ń wí yí ti sọ àìmọye mílíọ̀nù èèyàn di aláìnílélórí tí ó sì túnmọ̀ sí pé ríra àwọn ẹlikọ́ptà yí ní oṣù Kẹfà ọdún 2024 yóò kó ipa ribiribi bá àgbéga irinṣẹ́ nǹkan ìjà ogun Nàíjíríà.

Ọ̀gágun Sadiq Garba tó ti fẹ̀yìntì nídì iṣẹ́ ológun ní Nàíjíríà jẹ́ èèyàn kan tó ti ń fọkàn tẹ̀lé ìdúnàdúrà nǹkan ìjà ológun yí láti ọdún 2022.

Ó ní ”bààlú abàsíbíòwú yí làwọn ológun ti ń lò láti ìgbà ogun Vietnam. Wọ́n máa ń gbe tẹ̀lé àwọn ọmọ ogun oríilẹ̀ tí a ṣì máa ṣáájú la ọ̀nà kí àwọn ọmọ ogun oríilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.”

Ó tẹ̀síwájú pé bàálù yí lágbára ”láti gbé ìbọn ẹlẹ́nu mẹ́ta tó lè yin ọ̀tá dé kìlómítà méjì tí a ṣì máa kó ọta ìbọn 750 sí ìkápá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ó tún lè gbé àwọn àdó olóró bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n lè fi ṣiṣẹ́ lálẹ”

Ó fikun pé àwọn bàálù yí á tún máa gbé ẹ̀rọ kòmpútà kan sára tí yóò jẹ́ kí wọ́n lè dá ààbò bo àwọn aráàlú.

Èyí ṣe pàtàkì láti dènà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé sẹ́yìn níbi tí wọ́n ti ṣèṣì pa àwọn aráàlú pẹ̀lú nǹkan ìjà ológun.

Ọ̀gágun Sadiq sọ pé látẹ̀hìnwá Amẹ́ríkà ń ṣọ́ra láti ta nǹkan ìjà olóró fún Nàíjíríà torí pé wọ́n á máa fi irúfẹ́ rẹ̀ ṣeku pa àwọn aráàlú.

Ó ní báyìí Amẹ́ríkà yóò ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tí yóò bá a wa bàálù yí.

”Ẹ̀rọ kọ̀mpútà inú bàálù yí yóò jẹ́ kí awakọ̀ bàálù rí nǹkan tó fẹ́ yìnbọn lù. Yóò lè sọ fún bóyá àwọn aráàlú tàbí àwọn jàndùkú ló fẹ́ yìnbọn lù. Ìrètí wa ni wí pé táa bá ní irú nǹkan ìjà ológun yí, kò ní sí irú àṣìṣe tó wáyé tí àwọn aráàlú ń farakásá lọ́wọ́ ikọ̀ ológun”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here