Àjọ̀dún ọdún Èṣù gbòde l’Ákùúrẹ́

Àjọ̀dún ọdún Èṣù gbòde l’Ákùúrẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìdálùú nì ṣèlú.
Àwọn oní ṣẹ̀ṣẹ kò mu ní kékeré ní Ìlú Àkúrẹ́ lọ́dún yìí papàá jùlọ àwọn eléṣù
bí wọ́n ṣe fi àfojúsùn àjọ̀dún ti ọdún yìí ṣe ìlanilọ́ye àti ìtanijí fún ará ìlú nípa nǹkan tí èṣù túmọ̀ sí àti ìyàtọ̀ tó wà láàrin Èṣù ọ̀dàrà tí Yorùbá àti Sátánì tí àwọn ẹlẹ́ṣìn kan mọ̀.

Àkòrí àjọ̀dún Èṣù ti ọdún yìí ni ‘A Walk with Èṣù ‘ ‘Ìrìnàjò pẹ̀lú Èṣù ’.

Aṣọ funfun làwọn oníṣẹ̀ṣe kó sí níbi àjọ̀dún náà pẹ̀lú oríṣiríṣi àkọlé bíi ” Esu is not Satan” “Èṣù Ọlá Ìlú” ” Láàlú Ògiri Òkò”.

Olórí awo ìlú Àkúrẹ́ olóyè Fayeye Fagbitẹ ló léwájú àwọn oníṣẹ̀ṣe ọ̀ún láti lọ bọ Èṣù tí Deji ti ìlú Àkúrẹ́ pẹ̀lú lílo epo, iyọ̀, ewúrẹ́, obì àti ọtí láti bọ èṣù lóríko náà.

Akọ̀wé àjọ ẹ̀sìn ifá Lágbayé, Akomolafe Wande sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá kò mọ bí Èṣù ṣe jẹ́ torí pé nnkan tí wọ́n gbọ́ kìí ṣe ìtàn tó jẹ́ òtítọ́.

Ó ní èyí wáyé látàrí ìgbìyànjú àwon akónilẹ́rú láti máṣe fẹ́ kí òótọ́ nípa Èṣù ṣe àwon ọmọ yorùbá lánfàní.

Ọ̀gbẹ́ni Akọmọlafẹ sọ síwájú pé Èṣù ní agbára láti tú àwọn èèyàn sílẹ̀ yàtọ sí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ lóde òní.

“àwọn bàbá wá mọ bí wọ́n ṣe ń lo èṣù láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. Èyí wá mú kí àwọn akónilẹ́rú tó wà pẹ̀lú ẹ̀sìn míràn gbìyànjú láti yí èrò àwọn ọmọ Yorùbá padà sí èyí tó ń rí Èṣù gẹ́gẹ́ bí ẹni aburú.

” Èṣù jẹ́ Ìránṣẹ́ pàtàkì fún elédùmarè tó sì má ń jíse fún elédùmarè tó dàbí ìlèkùn tó rí lé tósí ríta

Akọ̀wé àjọ ẹ̀sìn Ifa lágbayé náà tún tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé pé Èṣù ló ń Pín ire ká gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pè é ní ọlá ìlú, òun náà ló máa ń mú ìṣòdodo wà.

Akomolafẹ wá pàrọwà fún àwọn èèyàn kí wọ́n tẹ̀lé ìṣẹ̀ṣe ilẹ̀ wa kí ilẹ̀ Yorùbá lè bọ́ ní oko ẹrú, kí ìdàgbàsókè sì lè sun àwọn èèyàn rẹ̀ bọ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here