Toyin gbakú oníkú kú, ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ṣá a pa

Toyin gbakú oníkú kú, ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ṣá a pa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Yorùbá ní ole kò ní í ja àgbà ko má ṣe é lójú fìrí. Òwe yìí ló dífá fún owuyẹ kan tó sọ pé àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ṣekú pa akẹ́kọ̀ọ́ gbogbonìse tìjọba àpapọ̀ tó wà nílùú Ọffa, ní ìpínlẹ̀ Kwara, (Federal Polytechnic, Ọffa). Omidan Toyin Bamidele, tó wà ní HND1, lẹka tí wọ́n ti ń kọ nípa ìmọ nípa oúnjẹ (Food Technology), ni àwọn ìkà èèyàn kan ká mọ’nu ilé ẹ, tí wọ́n sì ṣá a pa síbẹ̀ .

Ọ̀kan lára àwọn tí ìṣẹlẹ náà ṣoju rẹ̀, ṣùgbọ́n tó ní ká má darukọ òun sọ pé ní nǹkan bíi aago mẹfa irọlẹ Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹrindinlogun, oṣù Kọkànlá yìí, làwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ọ̀hún ya bo agbègbè Dapson, níbi tí Toyin ń gbé nílùú Ọffa, pẹ̀lú àdá, àáké àtàwọn ohun ìjà olóró lọkan-o-jọkan, tí gbogbo àwọn èèyàn tó rí wọn sì ń rọ gìlàgìlà fún ẹmi wọn pẹ̀lú àwọn ohun ìjà olóró tí wọ́n kó dání ọ̀hún.

A gbọ́ pé yàrá Toyin ni wọ́n gbà lọ tààrà, bí wọ́n ṣe fojú kàn án ni wọ́n bẹrẹ sí ṣá a láàáké àti ad àdá bíi ẹran Iléyá, nígbà tí ẹmi bọ lára rẹ̀ tán ni wọ́n tóó fi sílẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n sì sá lọ.

Ó ní wọ́n lò tó iṣẹju mẹẹẹdogun kí wọ́n tó kúrò nínú yàrá Toyin, nígbà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ọ̀hún lọ tán làwọn tó ó wọ yàrá arẹwa obìnrin yìí, táwọn sì bá a nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n sì ti kun ún bíi ẹran.

Ẹni yìí ní èyí ló mú káwọn lọ fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn aláṣẹ ilé-ẹ̀kọ́ náà létí kí wọ́n lè gbé ìgbéṣẹ tó tọ.

Ó tẹ̀síwájú pé Toyin jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin ọ̀kan lára olórí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn igun kan, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n fẹ́ pa ìyẹn tó sá lọ ni wọ́n fi lọ pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Toyin Bamidele.

Wọ́n ní ó ti wà nínú àṣà àti ìṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ọffa Poli, kí wọ́n máa para wọn lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́-jáde, àti pé lọ́jọ́ Ajé, ọ̀ṣẹ tó kọjá yìí, ni wọ́n ṣe ayẹyẹ náà, tí wọ́n sì pa akẹ́ẹ̀kọ́ kan tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ọ̀hún síwájú géètì ilé-ẹ̀kọ́ yìí. Àwọn ọlọ́pàá ló padà lọ palẹ̀mọ́ òkú ọ̀hún.

Àwọn aláṣẹ iléẹ̀kọ́ náà ti fòfin de ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́-jáde tí wọ́n tún máa ń lọ ṣe níta ilé-ẹ̀kọ́, kí wọ́n lè raaye pa ẹni tí wọ́n bá fẹ́ pa nínú wọn, nítorí pé lọ́jọ́ náà gan-an ni ọjọ́ ikú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa máa ń pé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here