Oladips olórin tàka-súfèé yìí kánjú kú lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n

Oladips olórin tàka-súfèé yìí kánjú kú lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìbànújẹ́ ni kí màjèsín ó tojú òbí rọ̀run.
Ọladipupọ Ọlabọde Ọladimeji gan-an lorúkọ akọrin tó dolóògbé yìí, ṣùgbọ́n Oladips lọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ ọ́ sí lágbo orin tàka-súfèé

Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn ni Oladips jẹ́.

Ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹta ọdún 1995 ni wọ́n bí Oladips ọ̀dọ́mọdé olórin tó di olóògbé yìí.

Olórin tàka-súfèé ni, ó tún máa ń kọ orin sínú ìwé fáwọn olórin mí-ìn láti gbé jáde.

Ọdún 2012 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin, orin tó kọ́kọ́ kọ ló pè àkòrí rẹ̀ ní ‘SUCCESSFUL.’

Ìfigagbága tí D’banj gbé kalẹ̀ tó pè ní ‘King is here’ ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ Oladips, nítorí òun ló gbégbá orókè nínú ètò náà.

Ibẹ̀ ló sì gbà wọ iléeṣẹ́ Reminisce tó ń gbé àwo jáde pẹ̀lú Edge Records.

Àwọn orin olóògbé yìí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni Ajala, Mainland 2 Island toun ati Zlatan jọ kọ àti Lalakukulala tóun àti Reminisce jọ kọ papọ̀

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here