Ọwọ́ tẹ adigunjalè yìí , ṣe ló ń kà bòròbòrò níwájú ọlọ́pàá

Ọwọ́ tẹ adigunjalè yìí , ṣe ló ń kà bòròbòrò níwájú ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ni ti oníǹkan.
Ọkùnrin kan, Alao James, ti ń káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́ ni olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn tó wà ní Eleweeran, lórí ohun tó mọ̀ nípa mọ́tò kan tí wọ́n rí ní sàkání rẹ̀.

Láìpẹ́ yìí ni wọ́n jí mọ́tò Toyota Rav4 SUV , aláwọ̀ búlúù tó jẹ́ ti Elogie Polycap, gbé nílé ìgbọ́kọ̀sí kan tó páákì rẹ̀ sí lágbègbè Gbagada.

Nígbà tí Polycap lọ fi ìṣẹlẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá agbègbè Sango létí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ lórí ẹ̀, kò sì pẹ púpọ̀ tí wọ́n fi ri mọ́tò náà.

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn, SP Ọmọlọla Odutọla, ṣàlàyé nínú àtẹ̀jáde kan pé ìwádìí kíkún tí àwọn ọlọ́pàá ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà ló jẹ́ kí ọwọ́ tẹ James níbi tó farapamọ́ sí.

Odutọla fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé agbègbè Ilu Ọta, ni ọkùnrin afurasí ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta náà sá pamọ́ sí kí ọwọ́ tóó tẹ̀ ẹ́.

Ó ní gbogbo àwọn ẹ́síbíìtì tí wọ́n bá lọ́wọ́ rẹ̀ ni wọn yóò kó fún àwọn ọlọ́pàá agbègbè Gbagada, níbi tí wọ́n ti jí mọto ọ̀hún.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here