Mi o le sun leyin ti enikan fun mi ni ebun milionu kan naira fun igba akoko – Timi Dakolo
Gbajumo olorin Naijiria ati eni to n ko orin sile, Timi Dakolo ti seranti bi o se ri milionu kan naira akoko gba.
Ninu iforowanilenuwo pelu atokun eto, Chude Jideonwo, Dakolo safihan pe milionu kan naira oun akoko je ebun lati owo “alaanu Samaria” kan eni to ri oun lori mohunmaworan nigba ti oun n dije ninu Idols West Africa ni 2007.
O wi pe ebun naa tobi loju oun to fi je pe oun ko le sun ati pe o yi oun pada.
Dakolo wi pe, “O ni enikan kan ti mi o mo ri to fun mi ni milionu kan naira. Mi o ti ri egberun mewa naira ri. Owo ti mo n ri nigba naa ni egberun kan ati oodunrun naira, egberun kan din ni igba naira, egberun kan le ni igba naira, ati ilaji egberun kan. Enikan si fun mi ni milionu kan naira ni ebun owo. O wa so fun ile itura naa lati fun mi ni milionu kan naira. O ni oun kii wo mohunmaworan sugbon oun ri mi lori mohunmaworan ati pe oun ro pe ki oun fun mi ni milionu kan naira.
“Mo ri milionu kan naira, mi o le sun. Mo n wo owo naa. Mo so pe, ‘Owo yii yoo yato.’ Mo n so ede Geesi ni ojo naa. Emi ti mo maa n daamu gbogbo adugbo, mo dake roro [sic]. Mo ri ara mi ti mo n so ede Geesi to dara.”
Timi Dakolo di olokiki leyin ti o jawe olubori ninu idanileko Idols West Africa ni 2007.
Asáájú ni mo jẹ́ fún Pete Edochie ní ilé isẹ́ fíìmù – Kanayo O Kanayo
Ilumooka osere tiata Naijiria, Kanayo O. Kanayo, ti so pe asaaju ni oun je si akegbe oun to ju oun lo, Pete Edochie, ninu ile ise fiimu Naijiria, ti a mo si Nollywood.
Kanayo so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo kan nibi to ti n soro lori itan ile ise naa.
Ninu fonran to n lo kaakiri bayii, Kanayo wi pe oun darapo mo ile ise fiimu Naijiria fun bii odun merin saaju ki Pete Edochie to farahan ni igba akoko ni ile ise naa.
“Mi o se fowo ro seyin ninu akosile tabi itan nigba ti won ba n so ti ile ise fiimu Naijiria (Nollywood).
“E o le yo kuro pe Kenneth Nnebue se fiimu agbelewo akoko ni 1992. E o le yo kuro lara awon to kopa ninu fiimu ‘Living in Bondage’, bi e o se lo yo kuro lara okodoro oro pe ‘Things Fall Apart’ eyi ti Pete Edochie kopa ninu re kii se fiimu agbelewo. Sinema ni.
“Nitori naa ti e ba fe ko itan bayii ki e so pe Pete Edochie ju mi lo ni ile ise fiimu Naijiria, maa jiyan re nitori pe o ba mi lenu ise naa ni.
“Nitori naa, ti o ba kan oro sinema, bee ni, e le lo ba Baba Hubert Ogunde ni 1940 tabi 1950. Akosile naa niyi.