Asáájú ni mo jẹ́ fún Pete Edochie ní ilé isẹ́ fíìmù – Kanayo O Kanayo
Ilumooka osere tiata Naijiria, Kanayo O. Kanayo, ti so pe asaaju ni oun je si akegbe oun to ju oun lo, Pete Edochie, ninu ile ise fiimu Naijiria, ti a mo si Nollywood.
Kanayo so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo kan nibi to ti n soro lori itan ile ise naa.
Ninu fonran to n lo kaakiri bayii, Kanayo wi pe oun darapo mo ile ise fiimu Naijiria fun bii odun merin saaju ki Pete Edochie to farahan ni igba akoko ni ile ise naa.
“Mi o se fowo ro seyin ninu akosile tabi itan nigba ti won ba n so ti ile ise fiimu Naijiria (Nollywood).
“E o le yo kuro pe Kenneth Nnebue se fiimu agbelewo akoko ni 1992. E o le yo kuro lara awon to kopa ninu fiimu ‘Living in Bondage’, bi e o se lo yo kuro lara okodoro oro pe ‘Things Fall Apart’ eyi ti Pete Edochie kopa ninu re kii se fiimu agbelewo. Sinema ni.
“Nitori naa ti e ba fe ko itan bayii ki e so pe Pete Edochie ju mi lo ni ile ise fiimu Naijiria, maa jiyan re nitori pe o ba mi lenu ise naa ni.
“Nitori naa, ti o ba kan oro sinema, bee ni, e le lo ba Baba Hubert Ogunde ni 1940 tabi 1950. Akosile naa niyi.