Gííwá Fásitì Adekunle Ajasin ṣàbẹ̀wò sí ẹ̀ka rẹ̀ n’Ìbàdàn

Gííwá Fásitì Adekunle Ajasin ṣàbẹ̀wò sí ẹ̀ka rẹ̀ n’Ìbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gííwá Fásitì Adekunle Ajasin Ọ̀jọ̀gbọ́n Olugbenga Ebenezer Ige, ti ṣàbẹ̀wò sí ẹ̀ka Fásitì náà èyí tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ Òlùkọ́ni Ṃufutau Lanihun n’Ìbàdàn lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹfà oṣù kọkànlá ẹ̀gbàá okòóọdúnlémẹ́ta.
Àbẹ̀wò Gííwá náà ni láti wo ìgbaradì ẹ̀ka Fásitì ọ̀hún fún àbẹ̀wò Àjọ tó n ṣègbéléwọ̀n ìfòntẹ̀ lu ìdàngájíá àwọn Fásitì lórí àwọn ètò ẹ̀kọ́ gbogbo tí wọ́n ti buwọ́lù àti àfikún òmíràn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn èròjà àmúyẹ ìgbàlódé fún ètò ẹ̀kọ́.

Làsìkò àbẹ̀wò rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olugbenga fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé lọ́wọ́lọ́wọ́, Àjọ̀ National University Commission (NUC). wà ní Maraba,ní ìpínlẹ̀ Nasarawa,fúnrúfẹ́ ìgbéléwọ̀n yìí kan náà.

Gííwá Fásitì ọ̀hún jẹ́ ó di
mímọ̀ pé, àbèwò àjọ(NUC) yìí ṣè pàtàkì sí ìdáhùn fífí òntẹ̀ lu àgbénde ìlànà ẹ̀kọ́ Fàsitì ọ̀hún ,ọlọ́gbarangandan tó fi mọ́ gbígboyè ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì àti àwọn mìíràn lẹ́ka rẹ̀ tó wà ní Ìbàdàn.

Nínú ọ̀rọ̀ ti ẹ̀, aṣojúdarí Fásitì Adekunle Ajasin ẹ̀ka ti Ìbàdàn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Taiwo Gbolagade, fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí àbẹ̀wò ẹnu iṣẹ́ tí Gííwá náà ṣe sí ẹ̀ka Fásitì ọ̀hún n’Ìbàdàn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Taiwo kò sàì mu
dá Gííwá ilé-ẹ̀kọ́ ọ̀hún lójú pé ojú òpó tí Fásitì náà là sílẹ̀ ni àwọn n tọ̀ látìgbàyí wá, àti pé àwọn yóó tẹ̀síwájú ní gbogbo ọ̀nà látí ríi pé àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí yóó mú kí wọ́n dántọ́ láti lè fagagbága pẹ̀lú àwọn akẹẹgbẹ́ wọn káàkiri orílẹ̀.
Àbẹ̀wò Gííwá fásitì ọ̀hún ló n ṣàfihàn ìjáfá ohun ìkógìírí mọ́ṣẹ́ èyí tó n fi gbogbo ìgbà mú kí ìràwọ̀ fásiti náà ó máà gbókè tàn kárí ayé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here