Ojú òpópó orílẹ̀ yìí tí di pàkúté ikú láse ra ọkọ̀ Land Cruiser – Àwíjàre aṣòfin àgbà

Ojú òpópó orílẹ̀ yìí tí di pàkúté ikú láse ra ọkọ̀ Land Cruiser – Àwíjàre aṣòfin àgbà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iṣẹ́ ìlú kò ṣe é gira ṣe.
Ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà ti ní kò sí ohun tó burú nínú pé àwọn fẹ́ ra ọkọ̀ Toyota Landcruiser tuntun fún àwọn ọmọ ilé aṣòfin àpapọ̀.

Iye tí ọkọ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fẹ́ rà jẹ́ ọgọ́jọ mílíọ̀nù náírà yàtọ̀ sí ọkọ̀ arọ́ta ìbọn dànù tí wọ́n fẹ́ rà fún Ààrẹ ilé aṣòfin àti igbákejì rẹ̀ Godswill Akpabio àti Barau Jibrin.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ àwọn aṣòfin náà pé wọn kò bìkítà bí ìyà ṣe ń bá ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí fínra tí wọ́n fi fẹ́ kó ọ̀bítíbitì owó láti fi ra ọkọ̀.

Àjọ Human Rights Writers Association (HURIWA) ní bí ìgbà pé àwọn aṣòfin náà fẹ́ mọ̀ ọ́n-mọ̀ tigi bọ àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú ni èròńgbà láti ra àwọn ọkọ̀ náà lásìkò tí àwọn kan kò rí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mẹta jẹ ní oòjọ́.

HURIWA ní owó tí wọ́n fẹ́ fi ra àwọn ọkọ̀ náà ló yẹ kí wọ́n fi ṣe àwọn nǹkan amáyédẹrù sí ìlú.

Bákan náà ni àjọ Socio-Economic Rights and Accountability Project (SERAP) ní kí ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ dá ilé aṣòfin àpapọ̀ dúró lórí ọkọ̀ tí wọ́n ń gbèrò láti rà náà.

Àmọ́ ilé aṣòfin àgbà ní àwọn aṣòfin nílò àwọn ọkọ̀ ọ̀hún fún iṣẹ́ wọn ni àwọn ṣe fẹ́ ra àwọn ọkọ̀ náà.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, alága ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn aṣòfin Sunday Karimi ní bí àwọn èèyàn ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn kò dára tó.

Karimi ní ọ̀pọ̀ àwọn Mínísítà ló ní ọkọ̀ mẹ́ta tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ àmọ́ àwọn ni àwọn ọmọ Nàìjíríà máa ń dójú ìjà kọ.

Ó ní ó yẹ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà máa tọná wádìí àwọn Mínísítà àtàwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ wọn ló ń lo àwọn nǹkan tó dára ju ti àwọn lọ.

“Ọ̀pọ̀ àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ ni àwọn gómìnà ti máa ń ra ọkọ̀ bọ̀gìnì kalẹ̀ fún kí wọ́n tó búra wọlé fún wọn kódà bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀.”

Ó fi kun pé nítorí àwọn ọ̀nà Nàìjíríà tí kò dára ni àwọn ṣe fẹnukò láti ra Land Cruiser kí ó lè tọ́jọ́.

Karimi ṣàlàyé pé tí òun bá lọ sí ẹkùn tòun ń ṣojú nílé aṣòfin àgbà, owó kékeré kọ́ ni òun máa ń ná sí ọkọ̀ nítori àwọn ọ̀nà tí kò dára.

Ó ní àwọn kò bá tún ra àwọn ọkọ̀ ọ̀hún lọ́wọ́ àwọn tó ń pèsè ọkọ̀ ní Nàìjíríà àmọ́ iye àtàwọn nǹkan míì ló jẹ́ kí àwọn padà pinnu láti ra SUV náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here