Aiyedatiwa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Akeredolu, gómìnà fárígá

Aiyedatiwa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Akeredolu, gómìnà fárígá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ibi tí erin méjì bá ti kọlura kóóko ibẹ̀ ni yóó jìyà.
Gómìnà Akeredolu àti igbákejì rẹ̀, Aiyedatiwa
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kọ ẹ̀bẹ̀ tí igbákejì rẹ̀, Lucky Aiyedatiwa rawọ́ rẹ̀ sí i lórí làásìgbò tó ń wáyé lórí ètò òṣèlú tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.

Akeredolu tó ń fèsì sí ẹ̀bẹ̀ Aiyedatiwa gba ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́, Doyin Odebowale ní Aiyedatiwa ní ẹjọ́ láti jẹ́ níwájú ìgbìmọ̀ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ṣáájú ni Aiyedatiwa ti di gbogbo ẹ̀bi àwọn wàhálà tó ń wáyé lágbo òṣèlú ní ìpínlẹ̀ Ondo ru àwọn olóṣèlú bó o ba o pá, bó ò ba, o bù ú lẹ́sẹ̀.

Ó ní gbọingbọin ni òun wà lẹ́yìn gómìnà Akeredolu bíi iké àti pé òun kò lọ́wọ́ nínú ìwọ́de kankan tako Akeredolu.

Igbákejì gómìnà sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn tó pè lọ́jọ́bọ̀ láti fi tọrọ àforíjì lọ́wọ́ gómìnà.

Ó ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ àti ọgbẹ́ ọkàn fún òun pẹ̀lú gbogbo ìdójútì tí gómìnà Akeredolu ti kojú látara àwọn ìròyìn tí kò dára tí wọ́n ń gbé kiri nípa ìpínlẹ̀ Ondo láti bí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.

Ó ní òun tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Akeredolu gẹ́gẹ́ bí gómìnà àti adarí àwọn ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Aiyedatiwa fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìpèníjà ìlera Akeredolu bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ àìgbọ́-ara-ẹni-yé látọwọ́ àwọn olóṣèlú bí ìpínlẹ̀ náà ṣe ti ń múra sílẹ̀ fún ètò ìdìbò sípò gómìnà lọ́dún 2024.

“Ó pọn dandan fún mi láti sọ ní gbangba pé èmi àti Gómìnà Akeredolu kò fìgbà kankan ní gbọ́nmi si omi ò to àti pé kò sí ìgbà kankan tí òun fojú kéré rẹ̀.”

Igbákejì gómìnà wá kan sáárá sí Akeredolu àti adarí àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC fún ipa tí wọ́n kó láti paná aáwọ̀ òṣèlú tó dìde ní ìpínlẹ̀ náà àti ọ̀nà tí gómìnà gbà láti fi bá àwọn ilé aṣòfin sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà láti fi paná aáwọ̀ òṣèlú dípò ìyọninípò.

Ẹ̀wẹ̀, Odebowale nínú àtẹ̀jáde tó fi síta tako Aiyedatiwa pé gómìnà Akeredolu kò ní kí ilé aṣòfin má ṣe iṣẹ́ wọn bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣe é.

Ó fi kun bákan náà pé irọ́ ni Aiyedatiwa ń pa pé òun kò lọ́wọ́ nínú ìwọ́de kankan tako gómìnà Akeredolu.

Ó ní gómìnà Akeredolu tó jẹ́ àgbà am òfin fúnra rẹ̀ kì í dá sí ọ̀rọ̀ àwọn aṣòfin nítorí ó mọ̀ pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn láìsí ìdíwọ́ kankan lábẹ́ òfin àti pé gómìnà kò bẹ àwọn aṣòfin láti dá ìgbésẹ̀ láti yọ Aiyedatiwa dúró.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here