Ilé aṣòfin Òndó sì ń dọdẹ yíyọ igbákejì Gómìnà nípò

Ilé aṣòfin Òndó sì ń dọdẹ yíyọ igbákejì Gómìnà nípò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀,bí wọ́n ṣe n pàkan lòmíràn n rú tú ú.
Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Òndó ti kọ ìwé ìpè tuntun ránṣẹ́ sí adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ náà, adájọ́ Olusegun Odusola, pé kó ṣe àgbéǹde ìgbìmọ̀ tí yóó tọpinpin ẹ̀sùn aṣemáṣe tí wọ́n fi kan ìgbákejì Gómìnà, Ọ̀gbẹ́ni Lucky Aiyedatiwa.

Ìwé náà ti olórí ilé, Olamide Oladiji buwọ́lù, ṣàlàyé pé ilé tẹ̀síwájú láti gbé ìgbésẹ̀ yíyọ ìgbákejì Gómìnà náà lẹ́yìn tí gbèdéke àṣẹ tí ilé ẹjọ́ gíga gbé kalẹ̀ wá sí òpin.

Ìwé náà sọ pé ”Lọ́jọ́ kẹta oṣù kẹwàá ni ilé bèèrè pé kí Olúwa mi ó ṣe àgbéǹde ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje, tí yóó ṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀sùn aṣemáṣe tí ilé fi kan Lucky Aiyedatiwa, ni ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin Nàìjíríà .”

Ó fi kún un pé, adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ náà ló ti fi àákè kọrí tẹ́lẹ̀ pé òun kò ní gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ oluwádìí náà, bí wọn kò bá yanjú àṣẹ tí ilé ẹjọ́ gíga ti pa ṣaájú nípa ìgbésẹ náà.

Àmọ́ ó ní ní báyìí tí gbèdéke lórí àṣẹ tí ilé ẹjọ́ gíga gbé kalẹ̀ ti wá kọjá, ilé aṣòfin ní àsìkò ti tó, bẹ́ẹ̀ sì ni ààyè wà kí adájọ àgbà ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ ìwádìí yìí.

Ìgbésẹ̀ tí ilé aṣòfin fẹ́ gúnlè báyìí ń wáyé lẹyìn bí ọ̀sẹ̀ kan tí ilé kéde pé àwọn ti káwọ rọ̀ lórí ìyọni nípò igbákejì Gómìnà lẹ́yìn tí àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress APC dá si ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here