Ọwọ́ ọlọ́pàạ́ ìpínlẹ̀ Ògùn tẹ ọkùnrin tó fipá bá wòlíìbìrin láṣepọ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì

Ọwọ́ ọlọ́pàạ́ ìpínlẹ̀ Ògùn tẹ ọkùnrin tó fipá bá wòlíìbìrin láṣepọ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìwé mímọ́ sọ pé bí òpin ayé bá kù dẹ̀dẹ̀, onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ à gbọ́ ṣe hàà ni yóó ṣẹ̀lẹ̀ ọ̀kan ni èyí, tí Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn ṣẹ̀rí ẹ̀ pé ọwọ́ àwọn ti tẹ ọkùnrin, ẹni ogójì ọdún kan, Lekan Sunday, ti wọ́n fi ẹ̀sùn kan pé ó f’ipá bá wòlíì obìnrin láṣepọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì.

Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n sọ pé Sunday f’ipá bá wòlíì obìnrin náà láṣepọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, tó wà ládugbó Ilogbo Adu, Kemta nílùú Abẹokuta, kí ọwọ́ tó tẹ̀ ẹ́ .

Ojú oorun ni wọ́n sọ pé ìyá wòlíì náà wà nígbà tí Sunday fi digun wọ ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀hún pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà, kí ó tó fi tipátipá ṣí ìyá wòlíì náà láṣọ wò lẹ́yìn tó ti dúnkookò mọ́ ọ.

Ìròyìn tó tẹ wá lọ́wọ́ sọ pé ní ṣe ni Sunday yọ ọ̀bẹ sí obìnrin náà, tó sì fi halẹ̀ mọ́ ọn pé bí kò bá gbà nǹkan tóun wá ṣe, òun yóò gun pa.

Ìyá wòlíì náà pariwo ìbosi ará àdúgbò títí láì sí ẹni tó gbọ́ ariwo rẹ̀ rárá.

Nígbà tó ń f’ìdi ìròyìn ọhún múlẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọmọlọla Odutọla sọ pé iṣẹ́ bíríkìlà ni Sunday ń se lágbègbè Kemta.

Odutọla ní wòlíì náà dá Sunday mọ̀ dáadáa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé alẹ́ ló fi lọ ká a mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì láti ṣe iṣẹ́ ibi náà,

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Ògún náà ṣàlàyé síwájú síi pé ní kété tí ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ̀ ẹ́, ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀, kó tó di pé àwọn f’ójú rẹ̀ ba ilé-ẹjọ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here