Ní ìpínlẹ̀ Bayelsa, Ilé-ẹjọ́ wọ́gilé olùdíje Gómìnà APC níbò kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́

Ní ìpínlẹ̀ Bayelsa, Ilé-ẹjọ́ wọ́gilé olùdíje Gómìnà APC níbò kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́
Ọrẹ Òtítọ́jù
 Bí kò ṣe ju oṣù kan péré lọ mọ́, tí ètò ìdìbò sípò Gómìnà yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Bayelsa, ilé-ẹjọ́ gíga kan tó fìkàlẹ̀ sílùú Abuja ti wọ́gi lé olùdíje  fúnpò Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀hún lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Ọ̀gbẹ́ni Timipre Sylva, wọn ní kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ póun ń díje, kò sì kúnjú òṣùwọ̀n láti dupò ọ̀hún.
Onídàájọ Donaltus Okorowo, ló pàṣẹ lọjọ Ajé, ọjọ́ kẹsan-an, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 yìí, pé kí àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa, Independent National Electoral Commission, INEC, pa orúkọ olùdíje ọhún rẹ̀ nínú ìwé ìdìbò, kí wọn sì yọ ọ kúrò lára àwọn olùdíje lẹyẹ-o-sọka.
Ìdájọ́ yìí wáyé látàrí ẹjọ́ tí ọmọ ẹgbẹ́ APC ìpínlẹ̀ ọhún kan, Domosueyefa Kosomo pe loṣu Kẹfa ọdun yii, tako iyansipo Sylva ninu eto idibo abẹlẹ APC ti wọn ṣe loṣu kẹrin ọdun yii, olupẹjọ naa ni Sylva ti APC fa kalẹ yii ko lanfaani lati dije fun ipo gomina ipinlẹ naa mọ, nitori wọn si ṣebura wọle fun un sipo gomina lẹẹmeji ọtọọtọ labẹ iwe ofin ilẹ wa, iyẹn constitution, ti ọdun 1999 ta a n lo.
Lásìkò igbẹjọ, agbẹjọro olupẹjọ, Amofin-agba Abiọdun Amuda-Kannike ṣàlàyé pé ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọ́n ti búra wọlé fún Sylva sípò Gómìnà náà, kò sì lè díje wọlé fúnpò kan náà yìí lẹẹkẹta tó fẹ́ ṣe yìí, torí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò lòdì sí òfin tó wà ní isọri kejilelọgọrin, apa akọkọ iwe ofin ilẹ wa.
 Ó ṣàlàyé pé ọjọ́ kẹrinla, oṣù Kẹrin, ọdún 2007 ni àwọn aráàlú Bayelsa kọkọ dìbò fún olùdíje yìí, lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, to wa nigba yẹn, to si yege ibo ọhun, wọn bura fun lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun naa gẹgẹ bii gomina.
Àmọ́, lọjọ kẹẹẹdogun, oṣù Kẹrin ọdún tó tẹle e, ìyẹn 2008, ilé-ẹjọ́ ko-tẹ-mi-lọrun ti ẹjọ́ awuyewuye ẹsùn ìbò máa ń pẹkun si nígbà náà, yọ Slyva dànù, wọn ni ibo to gbe e wọle mẹhẹ, wọn sì pàṣẹ àtúndì ìbò latokedelẹ.
Àtúndì ìbò mí-ìn wáyé lọjọ kẹrinlelogun, oṣù Karùn-ún ọdún 2008 ọ̀hún, Sylva yii ló tún wọlé lẹẹkeji, tí wọ́n sì bura fún-un lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣù Karùn-ún lẹẹkeji, ipò yìí lo si wà títí di ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù Kínní ọdún 2012 tí sáà ọdún mẹrin rẹ̀ pé.
Olupẹjọ yìí ní òun fẹ́ kí ilé-ẹjọ́ wo ìṣẹlẹ̀ yìí lójú ìlà ohun tí òfin sọ pé wọ́n kò lè búra fún ẹni kan fún ipò kan náà ju ìgbà méjì lọ.
Nígbà tí Onídàájọ Okorowo ń gbé ìdájọ
 rẹ̀ kalẹ̀, ó ní fifa tí APC fa Sylva kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùdíje wọ́n tako òfin yìí, nítorí tó bá wọlé ìbò, yóò di ẹẹmẹta nìyẹn tí wọ́n ń dìbò yàn an sípò kan naa, ti wọ́n yóò sì máa búra fún un sípò Gómìnà, eyi tí kò bofin mu. Torí ẹ, ó wọgi le Mínísítà lórí ọrọ̀ epo rọbi tẹlẹri náà, ó ní kò kúnjú ìwọn láti dupò
Títí  dàsìkò tá a fi ń kó ìròyìn yìí jọ, kò tíì dájú bóyá Sylva yoo pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lórí èyí, tàbí ẹgbẹ́ APC yoo gbé ìgbésẹ̀ mí-ìn. Ọjọ́ kọkànlá oṣù Kọkànlá ọdún yìí ni ètò ìdìbò tuntun yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Bayelsa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here