Ó lágbára o! Wọ́n bá òkú ọ̀gá tó ni òtẹ́ẹ̀lì “Water View”, ninu yara kan n’llọrin
Fẹ́mi Akínṣọlá
Hùn! Ògédé ẹni Ọlọ́run bá pamọ́ nìkan ló yọ lọ́wọ́ ewu.
Títí di àsìkò yìí , kò tí ì sẹ́ni tó mọ ohun tó ṣokùnfà ikú Adeniyi Ojo, ọga olotẹẹli kan tí wọ́n ń pè ní Water View, tó wà lágbègbé GRA, nílùú Ìlọrin, ní ìpínlẹ̀ Kwara. Níṣe ni wọ́n kàn bá òkú rẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn yàrá òtẹ́ẹ̀lì rẹ̀, láì mọ irú ikú tó pa á.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara fi ṣọwọ́ sáwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án yìí, ló ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó ní ọkùnrin kan, Kẹhinde Ọlaṣẹinde, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì náà ló mú ẹ̀sùn wá sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pé àwọn rí òkú Olùdásílẹ̀ àti alákòóso iléètura Water View, nínú ọ̀kan nínú àwọn yàrá òtẹ́ẹ̀lì ọ̀hún, táwọn kò sì mọ irú ikú tó pa á.
Ajayi ní àwọn ti gbé ọkùnrin náà lọ sí iléèwòsàn, tí wọ́n sì ti fìdí ẹ múlẹ̀ pé ó ti kú. Ó fi kún un pé wọ́n ti gbé òkú olóògbé yìí lọ sí yàrá ìgbókùú-sí fún àyẹ̀wò láti mọ irú ikú tó pa á.
Ó ní Kọmísánnà ọlọ́pàá ní Kwara, CP Victor Ọlaiya, ti pàṣẹ kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ikú òjìji tó pa Adeniyi ní kíá.