Mo jé̩ ò̩dájú si àwo̩n ò̩ré̩bìnrin mi té̩lè̩rí – Ruger

Mo jé̩ ò̩dájú si àwo̩n ò̩ré̩bìnrin mi té̩lè̩rí – Ruger

Mary Fàgbohùn

Gbajumo olorin Naijiria, Michael Adebayo Olayinka, ti a mo si Ruger, ti so itan to wa leyin orin re ‘Dear Ex’ lati inu awo orin re akoko, ‘Ru The World.’

O ni iwuri fun orin naa wa lati inu awon ibasepo oun ateyinwa ninu eyi ti oun ti je eni to mo ti ara re nikan ni odo awon orebinrin oun teleri.

Eni odun metalelogun naa so pe oun je “odaju gidi” si awon orebinrin oun teleri bo ti le je pe oun “nifee won” gidi.

O so eyi ninu fonran kan to n lo kaakiri lori ayelujara.

Ruger wi pe, “Gbogbo ohun ti e gbo ninu awo orin naa je ohun to sele si mi. O ni orin yi ‘Dear Ex’ ninu awo orin mi, je nipa ibasepo meta kan ti mo wa ninu re ni igba kan naa.

“Mo je odaju si awon arewa obinrin wonyi mi o si fi won sile di igba to wu mi lati je ki won lo. E mo, mo kan n wa be mo si n lo bi o se wu mi ati pe won si n duro fun mi. Mo kan n lo anfaani re. Awon meteeta si se pataki fun mi.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here