Atiku la Tinubu mọlẹ l’Amẹrika, adajọ ni ki wọn ko satifikeeti fun un

Atiku la Tinubu mọlẹ l’Amẹrika, adajọ ni ki wọn ko satifikeeti fun un

Ọrẹ Òtítọ́jù
Ṣé àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá kò bá tí ì tán, èèyàn nlá kó ní-ín tí ì sinmi àròyé ní ṣíṣe bẹ́ ẹ̀ lọ̀rọ̀ dà báyìí bí Ilé-ẹjọ́ gíga agbègbè Àríwá Illinois, ìyẹn United State District Court in Norther Illinois, ṣe pàṣẹ pé ní kíá, tí kò gbọdọ̀ ju wákàtí méjìdínláàádọ́ta lọ, èyí tí í ṣe ọjọ́ méjì péré, kí Fásitì ìpínlẹ̀ Chicago, (Chicaago State University), kó gbogbo iwe-ẹri àti àwọn àkọọ́lẹ̀ Bọla Ahmed Tinubu tó wà níkàáwọ́ wọn sílẹ̀ fún Alaaji Atiku Abubakar, wọ́n ní gbogbo ìwé ọ̀hún gbọdọ̀ tẹ Atiku lọ́wọ́, ó pẹ́ tán, aago méjìlá msán ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 yìí, kò sì gbọdọ̀ pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Onidaajọ Nancy Maldonado, lo paṣẹ yii lọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, ọsu Kẹsan-an, ọdun yii, latari ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan ti Aarẹ ilẹ wa, Bọla Ahmed Tinubu, pe sile-ẹjọ naa, lati ta ko idajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan to ti kọkọ waye ṣaaju, ninu eyi ti Onidaajọ Jeffrey Gilbert ti paṣẹ pe ki Fasiti Chicago ti Tinubu loun ti kawe gboye ko gbogbo sabukeeti ati awọn akọọlẹ to fi kawe boode fun Atiku Abubakar, laarin ọjọ meji pere.

Idajọ to waye logunjo, oṣu Kẹsan-an, ọhun, ni ko tẹ Tinubu lọrun, eyi lo mu kawọn agbẹjọro rẹ, Amofin Victor Henderson ati Christopher Carmichael, sare pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun siwaju Adajọ Maldonado, wọn ni ko ba awọn yiiri aṣẹ ti Adajọ Gilbert pa ọhun wo, tori awọn o lero pe ile-ẹjọ Majisreeti rẹ lagbara labẹ ofin ilẹ Amẹrika lati pa iru aṣẹ gboogi bẹẹ, ati pe aṣẹ ọhun tẹ ẹtọ onibaara awọn, iyẹn Bọla Tinubu, ti i ṣe Aarẹ Naijiria loju, tori ofin kan nilẹ Amẹrika daabo bo ẹtọ oni-nnkan, wọn ni Bọla Tinubu funra rẹ lo le sọ fun fasiti ọhun lati ko iwe-ẹri ọhun boode fẹnikẹni, ati pe labẹ ofin naa, ẹni ti ko ba ba ni sanwo ileewe, tọrọ sukuu naa ko kan an lọwọ tabi lẹsẹ ko le maa beere pe ki wọn jẹ koun ri sabukeeti ẹni.

Wọn ni aṣẹ lati ko iwe-ẹri Tinubu boode ọhun yoo fa awọn ipalara ati ewu kan fun Aarẹ Bọla Tinubu, tori ẹ lawọn ko ṣe fara mọ ọn.

Wọn tun wi awijare pe to ba tiẹ waa di karangida, ti Atiku ba ni ohunkohun i ṣe pẹlu iwe-ẹri Tinubu, kidaa sabukeeti rẹ nikan ni ki wọn paṣẹ fun fasiti ọhun lati mu boode, ki wọn ma ṣe ko awọn iwe ati akọọlẹ yooku fun Atiku rara. Bẹẹ ni wọn tun ni ẹjọ nipa ijawe olubori Tinubu ninu eto idibo aarẹ to kọja ni Naijiria, eyi ti Atiku n tori rẹ wa iwe-ẹri Tinubu kiri yii, ẹjọ naa ti tẹnu bọpo, tori igbimọ onidaajọ Tiribuna ti dajọ pe Tinubu lo wọle ibo, ko si fi bẹẹ si ohun ti sabukeeti Tinubu le yi pada ninu idajọ ọhun to ba de iwaju awọn adajọ Supirimu kọọtu, iyẹn ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, eyi ti Atiku gbe ẹjọ lọ bayii.

Amọ niṣe ni Onidaajọ Maldonado da gbogbo awijare ati atotonu yii nu bii omi iṣanwọ ninu idajọ rẹ, o ni:

“Fun awọn idi ta a ti mẹnuba ninu iwe Ipinnu ṣiṣe ati aṣẹ kootu yii, iyẹn Memorandum Opinion and Order, ile-ẹjọ yii wọgi le Aarẹ Bọla Tinubu lori bo ṣe ta ko aṣẹ ti Adajọ Gilbert ti pa ṣaaju, ile-ẹjọ yii si fara mọ aṣẹ ọhun, ki aṣẹ naa mulẹ gẹgẹ bi Onidaajọ Gilbert ṣe pa a.

Nitori eyi, ile-ẹjọ yii faṣẹ si awọn ibeere ati ẹbẹ Atiku Abubakar, labẹ isọri kejidinlọgbọn iwe ofin USC, ti ọdun 1782.

Ẹ oo ranti pe Atiku Abubakar, ti i ṣe igbakeji aarẹ orileede yii nigba kan, lo dije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), loṣu Keji, nigba ti wọn kede Bọla Ahmed Tinubu, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) gẹgẹ bii ẹni to wọle ibo, ti wọn si bura fun un sipo aarẹ loṣu Karun-un, ọdun yii.

Lẹ́yìn tí ètò ìdìbò sípò Ààrẹ ti parí ni Atiku ti gba ilé-ẹjọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ láti bèèrè fún àwọn ẹdà iwe-ẹri Tinubu, ó lóun fẹẹ wo àwọn iwe-ẹri sẹkọndiri àti tí ọjọ́-orí tó fi wọlé sílé ẹkọ́ náà, òun sì fẹẹ mọ bóyá ọkùnrin ni Tinubu ọ̀hún ni tàbí obìnrin.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here