Ọkùnrin kan pàdánù $2.1 sórí ‘cryptocurency’

Ọkùnrin kan pàdánù $2.1 sórí ‘cryptocurency’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ wọ́n ní ajé ní-ín bojú ọ̀rẹ́ jẹ́.
Ní báyìí tí ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní ‘King of Crypto’ yóó máa jẹ́jọ́ lórí onírúurú ẹ̀sùn jìbìtì, ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan ti ṣàlàyé bí òun àti ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri àgbáyé ṣe pàdánù òbítíbitì owó sí iléeṣẹ́ Sam Bankman-Fried.

Títí di ìgbà tí iléeṣẹ́ náà fi lulẹ̀, Sunil Kavuri ṣì gbàgbọ́ pé Sam Bankman-Fried ṣì lè wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro tí wọ́n dojúkọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iléeṣẹ́ King of Cryotp ti ń dàwó, Sunil gbàgbọ́ pé kò sí ewu lóko.

Èyí kò ṣẹ̀yìn àwọn ìrírí rẹ̀ nípa ìdòwòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá ńlá bíi ilé ìfowópamọ́ àti bó ṣe máa ń ṣòwò crypto ṣaájú.

Ìgbàgbọ́ rẹ̀ pọ̀ nínú Sam Bankman-Fried tó bẹ́ẹ̀ tó fi sọ pé kò sí ewu lóko.

Ẹnu rẹ̀ ló wà títí tó fi rí àtẹ̀jíṣẹ́ pé kò sí ànfààní láti gba owó jáde mọ́.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí iléeṣẹ́ FTX, tó jẹ́ iléeṣẹ́ tó tóbi jùlọ lágbàáyé nípa pàṣípààrọ̀ cryptocurency ṣe lulẹ̀.

Gbogbo òógùn ojú Sunil fun ọjọ́ pípẹ́ ló bá iléeṣẹ́ náà lọ lẹ́yìn tó pàdánù owó tí iye rẹ̀ jẹ́ $2.1 níbẹ̀

Ìròyìn ní ọgbẹni Sunil ni ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó pàdánù owó tó pọ̀ jùlọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àmọ́ yàtọ̀ sí Sunil ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn bíi tirẹ̀ ló pàdánù owó nlá sílẹ́eṣẹ́ náà káàkiri àgbáyé, ó sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn èèyàn náà láti pe FTX lẹ́jọ́ báyìí.

Sunil ni “ẹnìkan tilẹ̀ wà lórílẹ̀-èdè Turkey tó jẹ́ pé $600 nìkan ló kù lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tó pàdánù gbogbo owó rẹ̀ ṣọ́wọ́ FTX, nígbà tí ẹlòmíràn ní South Korea ti dèrò ilé ìwòsàn .”

Sunil ti bẹ̀rẹ ìrànlọ́wọ́ fún àwọn èèyàn láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Canada, Argentina, Dubai, Turkey, Hong Kong, China àti Singapore lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Púpọ̀ nínú wọn ló ti di ẹdun arinlẹ̀, nígbà tí àwọn mìíràn pàdánù owó tó lé ní òbítíbitì mílíọ̀nù.

Gbogbo wọn ló ń dúró de ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.

Ẹ̀sùn méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ní ṣe pẹ̀lú ìwà jìbìtì ni àwọn aṣòfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà fi kan Sam Bankman Fried.

Ọkùnrin ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n náà, tó dá iléeṣẹ́ FTX ti sọ pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun, àmọ́ yóò pe ẹjọ́ tako àwọn ẹ̀sùn ọ̀hún.

Yàtọ̀ sí òun, àwọn lọ́gàlọ́gà níléeṣẹ́ rẹ̀ náà ti gbà pé àwọn jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, wọ́n sì ṣetán láti sọ̀rọ̀ lórí bí iléeṣẹ́ náà ṣe dà wó.

FTX jẹ́ iléeṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé wọ́n lè kó owó wọn lé lórí fún òwò crypto ṣíṣe.

Lára àwọn kátàkárà tí àwọn èèyàn lè ṣe níléeṣẹ́ náà ni Bitcoin, àtàwọn owó ayélujára mìíràn.

Mílíọ̀nù mẹ́ṣàn-án èèyàn ló bá iléeṣẹ́ náà dòwòpọ̀ láti àwọn orílẹ̀-èdè bíi ọgọ́rùn ún.

Nígbà tí iléeṣẹ́ ọ̀hún dàwó, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan èèyàn ni owó wọn bọ́ há nítorí wọn kò tètè gba àwọn owó náà jáde.

Kókó ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Sam Bankman Fried ni pé ó lo owó àwọn tó bá iléeṣẹ́ rẹ̀ dòwòpò fún àwọn òwò mí ìn fún ànfàní ara rẹ̀, àti láti ra àwọn ilé olówó ńlá, wọ́n ní ó tún bùn ún ọ̀pọ̀ olóṣèlú lówó fún ìpolongo ìbò.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here