Ìjọba kéde kónílé gbélé ni Kano lẹ́yìn ìdájọ́ Tribunal

Ìjọba kéde kónílé gbélé ni Kano lẹ́yìn ìdájọ́ Tribunal

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọn ní ìfura lògùn àgbà tí òye yé.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Kano ti kéde òfin kónílé gbé lé fún ọjọ́ kan lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ náà gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kano, Mohammed Usaini Gumel rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà láti tẹ̀lé òfin yìí nítorí pé àwọn ti da àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn sí ìgboro láti ṣe àmójútó òfin náà.

Gumel ní ìgbésẹ̀ ṣíṣe òfin kónílé gbélé yìí ń wáyé láti tẹ̀lé àṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ó ṣàlàyé pé ní aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ni òfin kónílé gbélé náà yóò wá sópin àti pé àwọn tó bá lòdì sí òfin náà yóò fojú winá òfin.

Kọmíṣọ́nà náà ṣàlàyé pé ojúṣe ọlọ́pàá ni láti ri dájú pé ààbò tó péye wà nílùú.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here