Òsèré tíátà, Osuofia, sò̩rò̩ lórí ikú o̩mo̩bìnrin re̩

Òsèré tíátà, Osuofia, sò̩rò̩ lórí ikú o̩mo̩bìnrin re̩

Mary Fágbohùn

Ogbontarigi osere tiata, Nkem Owoh ti a mo si Osuofia, ti soro lori iku omobinrin re keji, Kosisochukwu.

Eni odun merinlelogun naa di oloogbe leyin aisan ranpe ni ojo kejidinlogbon osu keje, 2023, ti won si te si isinmi ni Ojobo, ojo kerinlelogun osu kejo, si abule Amagu, Udi, ipinle Enugu.

Nigba to n soro lori isele laabi naa, Osuofia fi imoore re han fun gbogbo ife ati atileyin ti idile re gba ni akoko ti won n kedun naa.

O sapejuwe iku omo re owon o
naa bii ipadanu ti oun ko lero re rara.

“Mo fe dupe lowo gbogbo yin fun atileyin ati ife ti e fi han emi ati ebi mi. Nigba ti isele ibanuje yii waye, ko si ohun to bani ninu je bii pe ki o mo pe iwo nikan lo wa.

“Pelu imoore atinuwa ni mo fi gba iwe yin, ipe ibanikedun. A ti ri opolopo ayipada leyin odun die seyin. Sugbon ayipada yi ni mi o lero, mo si ni imolara ipadanu nla.

“Amo sa, mo mo pe nitori igbani niyanju yin, maa la akoko yi koja. E se fun iranlowo ti e se fun mi lati la ibanuje mi koja,” o ko o si oju opo Instagram ni ojo Aje.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here