Ẹ kú ojúlọ́nà ! UAE gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíría

Ẹ kú ojúlọ́nà ! UAE gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíría

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orílẹ̀-èdè United Arab Emirates(UAE) ti gbẹ́sẹ̀ kúrò l’órí òfin tó fi de ìwé ìrìnnà ọmọ Nàìjíríà sí orílẹ̀èdè ọ̀hún.

Ìgbésẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn tí Ààrẹ Bola Tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú Ààrẹ UAE, Sheikh Mohamed bin Zayed Al Nahyan nílùú Abu Dhabi ti í ṣe olú ìlú orílẹ-èdè ọ̀hún.

Ó ti pé oṣù mẹwàá báyìí tí ìjọba UAE ti fòfin dé àwọn arìnrìnàjò láti Nàìjíríà eléyìí tó sì ti ṣàkóbá fún ìdókòwò ọ̀pọ̀ èèyàn.

Nínú atẹjade tí olùdámọ̀rán Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ajuri Ngalale fisíta, ó ṣàlàyé pé ìpàdé Tinubu pẹ̀lú àwọn aláṣẹ UAE so èso rere.

Ngelale sọ nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún pé Ààrẹ Mohamed bin Zayed Al Nahyan fẹnu kò pẹ̀lú Tinubu lórí àwọn kókó kan tí yóò mú ìlọsíwájú bá ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.

Agbẹnusọ Ààrẹ ní ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Etihad àti ti Emirates tí wọ́n ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró tẹ́lẹ̀ ní Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà.

“Pẹ̀lú ìwé àdéhùn tí Tinubu àti Aarẹ UAE buwọ́lù yìí, ọpọ ìdókòwò ẹlẹ́gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù owó dọ́là ni yóò tibẹ̀ jáde ní Nàìjíríà.

Ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ológun, ètò àt’àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ ìjọba míì náà yóò jẹ́ ànfààní àdéhùn tuntun láàrin Nàìjíríà àti UAE,” Ngelale ṣàlàyé.

Bákan náà ni Tinubu tún buwọ́lu ìwé àdéhùn pẹ̀lú ìjọba UAE lórí ètò pàsípààrọ̀ owó ti orílẹ-èdè méjèèjì yóò máa kéde rẹ̀ láìpẹ́ .

Lákòótán, Tinubu gbóṣùbà fún Ààrẹ Al Nahyan fún ìpinu rẹ̀ láti fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà fún ànfàní orilẹede méjèèjì.

Lọ́dún tó kọjá ni ìjọba ilẹ̀ Dubai fòfin de àwọn ọmọ Nàìjíríà láti má lè ṣàbẹ̀wò sílẹ̀ náà mọ́.

Nínú àtẹ̀jáde tí Dubai fi léde, wọn kò sọ èrèdí pàtó tí wọn ṣe gbé ìgbésẹ̀ náà, wọ́n kàn sọ pé kò sí ààyè fún àwọn ọmọ Nàìjíríà láti wá sílẹ̀ Dubai mọ́ ni.

Ìgbésẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí wọ́n kọ́nọ́ kéde àwọn òfin tuntun kan nípa ìwé ìrìnnà ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Lásìkò náà ni wọ́n sọ pé àwọn kò ní fún ọmọ Nàìjíríà tí ọjọ́ orí rẹ̀ bá kéré ju ogójì ọdún lọ ní físà, pàápàá àwọn tó ń lọ láti gbafẹ́e .

Ó ti lé ní ọdún kan àbọ̀ tí Nàìjíríà àti Dubai ti ń forí gbárí lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan.

Nínú oṣù Kẹjọ ọdún tó kọjá, ẹnìkan lójú òpó abẹ́yẹfò rẹ̀ ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ti àwọn ọmọ Nàìjíríà kan mọ́ inú yàrá ní pápákọ̀ òfurufú Dubai.

Ẹni náà ní wọn kò ṣe dáadáa sí àwọn ọmọ Nàìjíríà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé wọn pé pérépéré.

Àmọ́ ìjọba Nàìjíríà, láti ẹnu adarí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà nílẹ̀ òkèèrè, Abike Dabiri-Erewa sọ pé níṣe ni àwọn ọmọ Nàìjíríà náà kò tẹ̀lé òfin tó rọ̀ mọ́ físà ọwọ́ wọn.

Ó ní “ Àwọn èèyàn náà gba físà tó yẹ kí wọ́n fi rìnrìn àjò pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àmọ́ lọ láì mú ẹbí wọn kankan dání .”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here