Guinness World Record, Ìdílé ọjọ́ ìbí kan náà gba àmì ẹ̀yẹ

Guinness World Record,
Ìdílé ọjọ́ ìbí kan náà gba àmì ẹ̀yẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá
Bóṣe wu olúwa ló ń ṣọlá Rẹ̀ fẹ́ni tó bá wù Ú,ó wá kèèyàn tí yóó bi Í léèrè.
Àwọn ètò kan wà tí ìfarajọ rẹ̀ kò wọ́pọ̀,lára irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ ni kí ènìyàn nínú ẹbí kan náà sùpọ̀ ní ọjọ́ ìbí kan náà pẹ̀lú ara wọn tí èyí kìí sì sábà wáyé lọ́pọ̀ ìgbà.

Ṣùgbọ́n fún ẹbí Mangi ní Larkana, orílẹ̀ èdè Pakistan, nǹkan tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wá ni àwọn ìdílé yìí ní papọ̀.

Àwọn mẹ́sàn-án ló wà nínú ẹbí yìí, bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ wọn méje èyí tí ìbejì méjì wà nínú wọn.

Ọjọ́ ìbí kan náà ni àwọn ẹbí yìí ní papọ̀. Ọjọ́ kìíní oṣù Kẹjọ ọdún ni ọjọ́ ìbí gbogbo wọn kódà ọjọ́ yìí gan ni bàbá àti ìyá yìí ṣe ìgbéyàwó.

Ní ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹjọ ọdún 1991 tó jẹ́ ìbí wọn ni Ameer àti Khudeja ṣe ìgbéyàwó tí wọ́n sì bí àkọ́bí ọmọ wọn lọ́jọ́ yìí kan náà lẹ́yìn ọdún kan.

Àwọn ọmọ méje tí Ameer àti Khudeja bí ló jẹ́ pé ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹjọ ni wọ́n bí gbogbo wọn.

Èyí ló jẹ́ kí orúkọ wọn ìwé àkọ́ọ́lẹ̀ àgbáyé nítorí kò ì tíì sí ìdílé mìíràn tí wọ́n ní irú àkọ́ọ́lẹ̀ yìí.

Ìdílé kan ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, ẹbí Cummins ni wọ́n ti kọ́kọ́ ní àkọ́ọ́lẹ̀ náà pẹ̀lú tó ṣe ogúnjọ́ oṣù kejì ni wọ́n bí gbogbo wọn nínú ìdílé wọn tó jẹ́ ti ènìyàn ẹlẹ́ni márùn-ún.

Ameer ní inú òun dùn tó sì ya òun lẹ́nu nígbà tí àwọn bí àkọ́bí ọmọ àwọn ní ọjọ́ ìbí òun àti ìyàwó òun.

Ó ní ìyàlẹ́nu ló tún jẹ́ fún àwọn nígbà tí àwọn tún ń bí àwọn ọmọ yòókù ní ọjọ́ kan náà àti pé àwọn ri gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Ó ṣàlàyé pé gbogbo àwọn ọmọ náà ni àwọn bí láti ìdí gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ àti pé àwọn kò lo iṣẹ́ abẹ láti fi bí ọmọ kankan rí.

Bákan náà ló ní àwọn dókítà kò lo abẹ́rẹ́ tàbí oògùn láti fi lè jẹ́ kí àwọn ọmọ náà tètè wá rí.

“Ẹ̀bùn ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kìí ṣe wí pé a gbèrò láti bí àwọn ọmọ wa sí ọjọ́ kan náà.”

Ó fi kun pé bíbí ìbejì ní ẹ̀ẹ̀mejì jẹ́ ohun tí kìí sábà wáyé lọ́dọ̀ àwọn tó sì ya àwọn lẹ́nu nígbà tí àwọn bí ìbejì ọkùnrin méjì ní ọdún 2003 tí àwọn sì tún bí obìnrin méjì ní ọdún 2008 ní ọjọ́ ìbí kan náà.

Ní ìdílé Mangi, ọjọ́ pàtàkì ni ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹjọ máa ń jẹ́ fún wọn.

Àkàrà òyìnbó kan ṣoṣo ni wọ́n máa ń lò láti fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí wọn dípò rírà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ameer àti Khudeja ní inú àwọn máa ń dùn pé àwọn àtàwọn ọmọ wọn ń ṣe ọjọ́ ìbí lọ́jọ́ kan náà àti pé ó máa ń dùn mọ́ àwọn ọmọ àwọn nínú.

Ameer ní nígbà tí wọ́n fún àwọn ní ìwé ẹ̀rí fún àkọ́ọ́lẹ̀ orúkọ àwọn nínú ìwé àgbáyé, ó ní òun rò ó pé Ọlọ́run ló fún òun láti fún ní gbogbo ògo.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here