Bó ṣe ń jó, ló ń ṣiṣẹ́ gidi l’Ọ́sun—-Obasanjo

Bó ṣe ń jó, ló ń ṣiṣẹ́ gidi l’Ọ́sun—-Obasanjo
,
Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ Nàìjíríà, Olóyè Olusegun Obasanjo ti ṣe káre sí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, Ademola Adeleke.

Obasanjo ní bí Adeleke ṣe ń jó fún Ọlọ́run, náà ló ń gbé àkànṣe isẹ́ ṣe ní ìpínlẹ̀ Osun.

Obasanjo gbósùbà bẹ́ẹ̀ fún Adeleke níbi ìsìn ìkórè kẹrìndínlógún ìjọ Love of Christ ti Wòlíì Esther Ajayi tó wà lágbègbè Victoria Island nilu Eko.

Lásìkò to ń sọ̀rọ̀ níbi ìsìn náà, Obasanjo yọ suti ètè sáwọn èèyàn tó ń fapa janu nípa bí Adeleke ṣe máa ń jó ijó àjókara.

Obasanjo wá yonbo Adeleke lórí bo ṣe ń jó náà, ó ní Ọlọ́run ló ń jó fún.

Obasanjo pé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi tó òun létí, ijó jíjó yìí kò dá àṣeyọrí Adeleke dúró torí ó ń ṣiṣẹ́ takuntakun bíi gómìnà ni ìpínlẹ̀ Osun.

Adeleke náà sì dìde lásìkò tí Obasanjo ń sọ̀rọ̀ yìí láti ṣe àpọ́nle ààrẹ àná náà.

“Jíjó ijó fún Ọlọ́run jẹ́ ohun ìwúrí, pẹ̀lú pé ó tún fi iṣẹ rere kun.

Ìròyìn to ń kàn mí láti sun jẹ àwọn ìròyìn ìdàgbàsókè tó ń wáyé nibẹ.

Ọlọ́run tó ń jó fún náà yóò da ìbùkún rẹ̀ lé ọ lórí àti ìjọba rẹ.

Bákan náà ni mo tún gbọ́ pé o jẹ gómìnà tó máa ń tẹ́tí sí aráàlú, wọ́n ní ó máa ń gba ìmọ̀ràn tọmọdé-tàgbà.

Inú mi dùn láti gbọ́ nípa èyí, mo sì ń ké sí Ọọ̀ni ilé Ife àtàwọn oríadé míràn níìpínlẹ̀ ọ̀sun láti ṣe àtìlẹ́yìn fún gómìnà Ademola Adeleke.

Èyí ni yóò jẹ ki ìṣẹ́ rere tó ń ṣe túbọ̀ tẹ̀síwájú.

Mo sì ń rọ gómìnà Adeleke náà láti ṣíṣẹ papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọba alayé, àwọn àgbààgbà àtàwọn èèyàn ti ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun jẹ lógún.”

Nígbà tó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ Obasanjo, Gómìnà Adeleke ni òun máa ń jó láti mọ rírí Ọlọ́run tó dá ayé àti ọ̀run, ojú kìí si ti òun láti jó fún.

” Ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì lọ́kùnrin lóbìnrin ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé máa di Gómìnà l’ọ́sun, èyí tó ti wá sí ìmúṣẹ báyìí.

Májẹ̀mú tí mo bá Ọlọ́run dá ní pe máa padà wa dúpẹ́, kí ń sì yín lógo gẹ́gẹ́ bí mo ti ń ṣe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìjọsìn.”

Adeleke wá mẹ́nuba ọ̀pọ̀ àṣeyọrí rẹ̀ láti ìgbà tó ti gorí àga gómìnà níìpínlẹ̀
náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here