Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀dá ọlẹ̀ ọmọ láì lo àtọ̀ àti ẹyin
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ohun kàyééfì gbáà ló jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣẹ̀dàá ọlẹ̀ ọmọ láì àtọ̀ ọmọkùnrin àti ẹyin ọmọbìnrin tàbí ilé ọmọ.
Àwọn onímọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Weizmann ní àwọn ṣẹ̀dàá ọlẹ̀ ọmọ láti ara àwọn sẹ́ẹ̀lì inú igi, tó sì jọ ọlẹ̀ ọmọ ọjọ́ mẹ́rìnlá.
Wọ́n ṣàlàyé àwọn èròjà tí wọ́n lò tó jẹ́ kí àyẹ̀wò rẹ̀ ṣàfihàn oyún nígbà tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò náà.
Àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ tí ìgbésẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ rí àyípadà gbòógì kan – bí wọ́n ṣe gba àwọn sẹ́ẹ̀lì náà jọ, tó fi yí padà sí ọmọ tó wà nínú oyún.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Jacob Hanna ti ilé ẹ̀kọ́ Weizmann Institute of Science ní ìgbà tí àyípadà yìí máa ń wáyé ń fa onírúurú àyípadà lára, ìmọ̀ kò sì tíì pọ̀ tó nípa rẹ̀.
Ìwádìí lórí ṣíṣẹ̀dá ọlẹ̀ ọmọ wáyé látara wíwà àlékún ìmọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè ṣẹ̀dàá nǹkan látara àwọn nǹkan tí wọn kò lérò.
Ìdàgbàsókè ti ń débá ẹ̀ka tó ń rí sí ẹ̀kọ́ nípa oyún.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní Isreal júwe ìwádìí tí wọ́n gbé jáde gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tó ń ṣàfihàn bí ọlẹ̀ ọmọ ṣe ń dàgbà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Hanna ní àpẹẹrẹ bí ọlẹ̀ ọmọ ènìyàn tó ti dàgbà fún ọjọ́ mẹ́rìnlá ṣe rí ni ìwádìí náà èyí tí kò ṣẹlẹ̀ rí.
Dípò lílo àtọ̀ àti ẹyin gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀, àwọn sẹ́ẹ̀lì láti ara igi ni wọ́n lò, tí wọ́n ṣe àtúnṣe rẹ̀ láti lè di onírúurú ẹ̀yà ara.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa lo àwọn kẹ́míkà kan láti fi mú àyípadà bá àwọn gíìnì rẹ̀ láti sọ́ di gíìnì mẹ́rin tó máa ń wà lára ìbẹ̀rẹ̀ oyún.
Àpapọ̀ sẹ́ẹ̀lì ọgọ́fà ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pò papọ̀ di ẹyọ̀kan tí wọn yóò sì fi ara balẹ̀ fún un.
Ìdá kan nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì tí wọ́n pò papọ̀ yìí ni yóò yí padà láti fi ara jọ ọlẹ̀ ọmọ ènìyàn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Hanna ní tí òdiwọ̀n àwọn sẹ́ẹ̀lì náà bá lọ déédé ní àyíká tó tọ́ yóò kàn bẹ̀rẹ̀ àyípadà náà fúnra rẹ̀.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa fi kalẹ̀ láti máa dàgbà láti jọ ọlẹ̀ ọmọ ènìyàn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnlá tí wọ́n ṣe ìdàpọ̀ rẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé “trophoblast” tí ó máa ń di ibi ọmọ àti ẹ̀yà tó máa ń gbé oúnjẹ láti inú ìyá sí ọmọ tí wọ́n ń pè ní “lacuna” ló wà lára rẹ̀.
Bákan náà ni àpò kan tó ń ṣiṣẹ́ ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín tó ń mú ọlẹ̀ ọmọ dàgbà ló wà lára rẹ̀.
Ìrètí tó wà nibẹ̀ ni pé àwọn ìwádìí báyìí máa ń rán àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ́wọ́ láti ṣàlàyé bí sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan ṣe ń jáde lára, rí bí ẹ̀yà ara ènìyàn ṣe ń dìde láti inú oyún.
Bákan náà ló máa ṣe àfihàn bí àwọn àìsàn kan tàbí òmíràn ṣe máa ń tọ ìran.
Ìwádìí yìí fi hàn pé ẹ̀yà ara ọlẹ̀ ọmọ kò ní dàgbà àyàfi tí ibi rẹ̀ bá ti kọ́kọ́ yí i ká.
Ó tún jẹ́ ọ̀nà láti mú ìlọsíwájú bá ìlànà oyún níní IVF nítorí ìmọ̀ yóò wà lórí àwọn nǹkan tó máa ń fa kí àwọn ọlẹ̀ ọmọ kan dúró tí àwọn mìíràn sì ń wálẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ ọ̀nà láti mọ̀ bóyá lílo oògùn nínú oyún jẹ́ ohun tó dára.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Robin Lovell Badge tó jẹ́ ẹni tó máa ń ṣe ìwádìí nípa ọlẹ̀ ọmọ ní ilé ẹ̀kọ́ Francis Crick Institute ní àwọn ìwádìí báyìí dára tí wọ́n sì máa ń dára lójú.
Ó ṣàlàyé pé ìtẹ̀síwájú gbọ́dọ̀ wà lórí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwádìí yìí kì í ṣe kẹ́sẹ járí.
Ó fi kun pé ó máa ṣòro láti mọ ohun tó máa ń jẹ́ kí oyún bàjẹ́ lára ènìyàn tàbí fà àìrí ọmọ bí, tí àwọn ìwádìí yìí kò bá máa ní àṣeyọrí.
Ìhà òfin sí ìwádìí yìí
Iṣẹ́ ìwádìí yìí ti ń fa ìbéèrè pé ṣé ó ṣeéṣe láti ṣe ìwádìí ọlẹ̀ ọmọ kọjá ọjọ́ mẹ́rìnlá.
Èyí kìí ṣe ohun tó lòdì sí òfin nítorí àwọn tí wọ́n ń lò láti fi ṣe ìwádìí yàtọ̀ sí ti ọlẹ̀ ọmọ gangan.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Lovell-Badge ní àwọn kan máa gba ìgbésẹ̀ náà wọlé tí àwọn mìíràn kò sì ní fi ara mọ.
Ó ní bí àwọn ọlẹ̀ ọmọ yìí bá sì ti ń jọ ti ènìyàn sí ni ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìbéèrè yóò máa tí ara rẹ̀ jáde.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Alfonso Martinez Arias ti ẹ̀ka imọ̀ Health Science ní ilé ẹ̀kọ́ Pompeu Fabra University ní ìwádìí náà ṣe pàtàkì púpọ̀.
Ó ní iṣẹ́ ìwádìí náà, fún ìgbà àkọ́kọ́ ṣàfihàn bí ọlẹ̀ ọmọ ṣe ń wáyé, ní èyí tí yóò mú ìwádìí nípa bí ẹ̀yà ara ṣe ń jáde lára wáyé láìpẹ́.