Géndé tó jí ìrẹsì lápòlápò dèrò ẹ̀wọ̀n

Géndé tó jí ìrẹsì lápòlápò dèrò ẹ̀wọ̀n

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ojú kókòrò òhun olè ọ̀kannkanhùn, ló mú kí wọ́n wọ́ Ọ̀gbẹ́ni Wale Sunday, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ iwájú adájọ ilé-ẹjọ́ Májísíréètì kan tó wà nílùú Badagry, ní ìpínlẹ̀ Èkó, Onídàájọ Fadahunsi Adefioye.

Ẹ̀sùn pé ó jí àpò irẹsi mẹta towó rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún Náírà (N99, 000) tó sì lọ tà á lówó pọọku fún oníbàárà rẹ̀ kan ni wọ́n fi kàn án.

Ọlọ́pàá olùpẹ̀jọ́, A.S.P Clement Okuoimose, tó fojú Sunday balé-ẹjọ́ sọ ní nǹkan bíi aago kan ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹsàn-án, ọdún yìí, ní Sunday ji apo irẹsi méta ọ̀hún níwájú ààfin Agahmathen, lágbègbè Ajara-Agahamathen, nílùú Badagry, nipinlẹ Èkó.

Ẹsùn méjì ọtọọtọ ni agbè fọba fi kan Sunday, ẹsùn àkọ́kó ni pé ó jí àpò irẹsi méta kan tí kì í ṣe ti rẹ̀ . Èkejì ni pé ó jalè láàrin ìlú. Gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí pátá ni olẹ̀pẹ̀jọ́ ní òfin ìlú Èkó kò fààyè gbà rárá.

Ó ní, ‘Iwọ Ọ̀gbẹ́ni Sunday, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ jí àpò ìrẹsì méta kan tó jẹ́ ti Ọ̀gbẹ́ni Usman Hammed. Inú mọ́tò ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Avalon ni oníṣòwò ìrẹsì ọ̀hún kó gbogbo ọjà rẹ̀ sí .’

Lẹ́yìn tí wọ́n ka gbogbo ẹsùn ọ̀hún sí i lẹ́sẹ̀ tán ni Sunday lóun gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan òun pátá.

Láì fàkókò ṣòfò rárá, Adájọ́ Adefioye ní kí wọ́n lọ ju Sunday sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Awhajigoh, tó wà nílùú Badagry. Ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 yìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here