È̩sìn ti fa ò̩pò̩lo̩pò̩ aburú ní Afrika – Agbéréjáde, Austin Faani
Mary Fágbohùn
Austin Faani, Oko ilumooka agberejade Naijiria ati osere tiata, Chacha Eke ti so pe esin fa opolopo aburu ju sise nnkan to dara lo ni Afrika.
Faani so eyi nigba to n safihan ohun ti o se nigba ti iyawo re ni aarun opolo.
Nigba to n ba awon eniyan Meticulous People Foundation Outreach, ile ise kan to n ri si oro awon alarun opolo, eyi ti Chacha je oludasile re, Faani seranti bii olusoaguntan kan se tan n lati se irubo pelu ewure ni ona lati mu ki ara iyawo re ya.
Nigba to fi fonran naa lede ni oju opo Instagram re, Chacha Eke ko o pe: “Gbogbo aye lo mo pe maa nilo ‘igbala’ nitori naa won ti ‘Austin Faani’ si ona mi.”
O wi pe: “Mo je eni to ni esin sugbon mo gbagbo pe esin ti se opolopo aburu si awon eniyan Afrika ju nnkan miran lo.
“Ni osu kokanla 2012, mo lo si ile ijosin kan nitori pe mo so fun olusoaguntan pe baba iyawo mi pa maalu pupo fun un, nitori naa o ni ki n pa nnkan fun un. Nitori naa mo sare lo si oja Abraka mo si ra ewure ti o tobi fun n sugbon ni opin gbogbo re, aisan naa ko kuro ni ara re.”