Tìbúnà dá Tinubu láre Obi àti Atiku kùnà pátápátá

Tìbúnà dá Tinubu láre Obi àti Atiku kùnà pátápátá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ tí a kò dá ni kìí kò,pin-in-pìn-pin ti pin báyìí lórí awuyewuye tó ń wáyé lórí àbájáde èsì ìdìbò sípò Aarẹ ilẹ̀ wa tó wáyé nínú oṣù Kejì, ọdún yìí, pẹ̀lú bí ilé-ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìdìbò ọ̀hún ṣe sọ pé Ààrẹ Bọla Tinubu tó wà nípò náà ló jáwé olúborí lásìkò ìdìbò ọ̀hún.

Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún tó jókòó láti gbọ́ ẹjọ́ kò tẹ́mi lọ́rùn tí àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ojúgbà rẹ̀ láti inú ẹgbẹ́ Labour, Peter Obi, àti ẹgbẹ́ APM pè ti dá ẹjọ́ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nù bíi omi ìṣanwọ́, wọ́n ni kò tẹ̀wọ̀n, kò sí àwíjàre nínú gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n rò kalẹ̀, wọ́n ní ẹni tó wà nípò Ààrẹ báyìí, Aṣíwájú Bọla Tinubu, tí àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wá kéde pé òun ló jáwé olúborí náà ló borí lásìkò ìbò yìí.

Nínú ìdájọ́ rẹ̀ ni adarí ìjókòó náà, Onídàájọ Haruna Tsammani, ti sọ pé pèlú gbogbo ẹ̀rí tó wà níwájú àwọn, Tinubu ló wọlé ìbò tó wáyé nínú oṣù Kejì, ọdún yìí, òun náà sì ni ilé-ẹjọ́ náà tún fòǹtẹ̀ lù pé ó wọlé nítorí òun ló ní ìbò tó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo àwọn olùdíje náà.

Ó fi kún un pé kò sí ọ̀kankan nínú àwọn olùpẹ̀jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n ní ẹrí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti fi gbe ẹjọ́ tí wọ́n pè ta ko olùdíje ẹgbẹ́ APC tó ti di Ààrẹ náà.

Àwọn adájọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó kù ni wọ́n wà lẹ́yìn Onídàájọ Tsmmani, tí wọ́n sọ pé Tinubu ló wọlé lẹyìn náà, wọ́n ní àwọn fara mọ́ ìdájọ́ rẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here