Alàgbà Taiwo Akinkunmi ṣe díẹ̣̀ lọ́rọ̀ Nàìjíríà kó tó tẹ́rígbaṣọ

  1. Alàgbà Taiwo Akinkunmi ṣe díẹ̣̀ lọ́rọ̀ Nàìjíríà kó
    tó tẹ́rígbaṣọ

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní aríṣe la rì kà,aríkà ni baba ìrègún,
ọkùnrin tó ṣe àsìá orílẹ-èdè wa, Nàìjíríà, Alàgbà Taiwo Akinkunmi (O.F.R), ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún lẹ́yìn tí wọ́n kí àwọn òbí ẹ̀ kú ewu. Ọ̀rọ̀ tí padà di ẹ kú aráfẹ́rakù fún ẹbí,ará,ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀.

Ọmọ rẹ̀, Akinkunmi Akinwunmi Samuel, ló sọ èyí di mímọ̀ lójú òpó ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀, níbi tí ó ti ṣèdárò bàbá tó bí i lọ́mọ ọ̀hún.

Ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún, ọdún 1936, ni wọ́n bí i. Ìyẹn ni pé ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún (87) ni bàbá náà lò lókè èèpẹ̀ kó tó dágbére fáyé

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú Ìbàdàn ni bàbá yìí ń gbé, ọmọ bíbí ìlú Òwu, ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ní í ṣe.

Ó lọ sílé ẹ̀kọ́ Baptist Day fún ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, àti Ìbàdàn Grammar School, fún ẹ̀kọ́ girama rẹ̀.

Akinkunmi gba iṣẹ́ ìjọba ní sẹkitéríàtì Ìbàdàn, lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ díẹ ló sì lọ sílùú Norway, níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀.

Ìlú Òyìnbó ló wà tó fi rí ìkéde kan pé wọ́n ń wá ẹni tí yóó ṣe àsìá tí Nàìjíríà yóò máa lò ní ìpalẹ̀mọ́ fún òmìnira orílẹ-èdè yìí.

Ọkùnrin ọmọ bíbí ìlú Owu yìí náà wà lára ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó dábàá irú àsìá tí Nàìjíríà lè máa lò, tìẹ ni wọ́n sì mú nínú àwọn èèyàn bíi ẹgbẹ̀rún méjì tó dán kinní ọ̀hún wò.

Àwòrán tó kọ́kọ́ ṣe ni àwọ̀ funfun láàrin pẹ̀lú àwọ̀ ewéko méjì, tí ìtànsan òòrùn sì wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ìgbìmọ̀ tó ṣàyẹ̀wò fún un ló yọ ìtànsan òòrùn yìí dànù.

Ìdí tí wọ́n ṣe mú ti Akinkunmi ni pé ó ṣàkótán àpèjúwe ilẹ̀ wa. Àwọ ewéko dúró fún àwọn igbó àti ohun àlùmọ́ọ́nì tó sodo sílẹ̀ wa, tí àwọ̀ funfun sì dúró fún àlàáfíà.

Ọjọ́ kin-in-ni, oṣù Kẹwàá, ọdún 1960, ni wọ́n ta àsìá yìí níbi ayẹyẹ òmìnira ilẹ̀ yìí, dípò àsìá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ ti ìjọba àwọn Òyìnbó amúnisìn.

Ọgọ́rùn-ún pọun (100€) nìjọba fún Akinkunmi fún iṣẹ́ ribiribi náà, tí ìjọba Ààrẹ tẹlẹ, Goodluck Jonathan, sì fi àmi-ẹ̀yẹ MON dá a lọ́lá lọ́dún 2014, lẹ́yìn tí ileegbimọ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kọ́kọ́ fún un lámì-ẹ̀yẹ lọ́dún 2013, lásìkò ìjọba Gómìnà Abíọ́lá Ajimọbi.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here