A ó ṣètò ìdìbò tó mọ́yánlórí láìpẹ́— Ológun adìtẹ̀gbàjọba Gabon

A ó ṣètò ìdìbò tó mọ́yánlórí láìpẹ́— Ológun adìtẹ̀gbàjọba Gabon

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní àìníláárí aráayé ní-ín múwọn rántí araọ̀run.
Olórí ìjọba ológun lórílẹ̀ èdè Gabon ti ṣe ìlérí láti dá agbára padà sọ́dọ̀ ìjọba alágbádá lẹ́yìn tí ètò ìdìbò tó bá òfin mu bá wáyé.

Ó sọ èyí lásìkò tó ń búra wọlé gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ fìdíhẹẹ́ ṣùgbọ́n kò sọ ọjọ́ pàtó tí ìjọba ológun yóò gbé agbára sílẹ̀.

Ògágun Brice Nguema léwájú ìdìtẹ̀gbàjọba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Ali Bongo lẹ́yìn ètò ìdìbò tó wáyé kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí.

Ọpọ àwọn èèyàn ló tú síta síbi ayẹyẹ ọhún, tí wọ́n sì tẹ́wọ́gba ìgbésẹ̀ ológun ọ̀hún.

Bákan náà ni àwọn mìíràn sọ pé ìjọba Ọ̀gágun Nguema ni ó jẹ́ ìtẹ̀síwájú ọdún márùndínlọ́gọ́ta ìdílé Bongo.

Bàbá Ali Bongo, Omar, wa ni ìjọba fún ọdún mọ́kànlélógójì kó tó kú ní ọdún 2009, ti ọmọ sì bọ́ sí ìjọba.

Ọ̀gágun, ẹni ọdún méjìdínláàdọ́ta lo gbogbo ọgbọ́n rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ológun nínú ìdílé Bongo, ti ọ̀pọ̀ sì rí i gẹ́gẹ́ bí i mọ̀lẹ́bí Bongo.

Nguema ni òun ti paá láṣẹ pé kí ìjọba tuntun yìí tú gbogbo àwọn olóṣèlú tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀.

Àwọn Mínísítà ìjọba tẹ́lẹ̀ wá síbi ibúra wọlé náà ṣùgbọ́n àwọn aráàlú pariwo mọ́ wọn.

Gabon ni orílẹ-èdè kẹfà tó gba òmìnira láti ilẹ̀ France ti ìjọba ológun ti gba ìṣàkóso ìjọba láàrin ọdún mẹ́ta

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here