Wọn ò san owó fún àwọn òsèré tíátà Naijiria bó se ye – Deyemi Okanlawon

Wọn ò san owó fún àwọn òsèré tíátà Naijiria bó se ye – Deyemi Okanlawon

 

Mary Fágbohùn

 

Osere tiata Naijiria, Deyemi Okanlawon ti safihan adojuko kan gboogi ti awon osere tiata n koju ni orile ede yi.

 

O ni awon osere ni ile ise fiimu Naijiria ni won o san owo fun bi o se ye.

 

Okanlawon so eyi nigba to farahan lori eto mohunmaworan MTV Base Africa, Lights, Camera Stardom, pelu akegbe re Daniel Etim-Effiong.

 

O wi pe, “Mo ro pe awon osere tiata [Naijiria] o gba owo ti o to. Ni ona miran, nipa ti isuna ohun ti a n ri ko to nnkankan lati se nnkan ti a ni ati lati lo o fun idaboobo ojo iwaju wa.”

 

Etim-Effiong fikun un pe: “Mo tun ro pe bi ile ise [fiimu Naijiria] se n sise, ko pese nnkan pupo fun awon osere lati sise nipa ti isuna ati ona miran.

 

“Fun apeere, mi o ro pe won n fun awon osere tiata ni akoko ti o to lati gbaradi [fun ipa ti won fe ko]. Mi o ro pe won n fun awon osere ni akoko pupo lati sise lori ara won.”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here