‘Padà, mi ò sí nílé’ – Davido sọ fún ọkùnrin tó gun kẹ̀kẹ́ láti Benue wáá ri i
Mary Fágbohùn
Gbajumo olorin, David Adeleke, ti a mo si Davido, ti pase fun afenifere ti inu re dun kan to wo irinajo oju popo lati ipinle Benue wa si Eko pelu keke re lati wa ri i pe ki o “pada.”
Enikan lori Twitter, @ssbbmuzi ti fi awon aworan afenifere naa lede ni oju opo re @emmiwuks, wi pe o n gun keke bo lati Benue lati pade Davido.
O so pe afenifere naa ti lo ojo mejo ni oju ona bayii.
Eni naa lori Twitter ko o pe, “Omokunrin ti a n pe oruko re ni @emmiwuks bere irinajo lati Benue si #Eko lori keke lati pade# onirawo olorin takasufe @davido, o ti lo ojo mejo ni oju ona loni.”
Davido tun oro naa gbe jade o si pase pe ki afenifere naa pada, o fikun un pe oun ko si ni orile ede lowo yi.
Olorin naa ko o pe, “Yi pada mi o si nile.”