Ìjọba ológun Burkina Faso ti iléeṣẹ́ rédíò kan pa ní Niger
Ọrẹ Òtìtọ́jù
Àwọn ológun tó ń ṣèjọba lórílẹ̀-èdè Burkina Faso, ti tiléeṣẹ́ rédíò kan tí wọ́n ń pè ní ‘Omega Radio Station,’ tó wà lórílẹ̀-èdè náà pa pátápátá, kò sì sẹ́ni tó mọ ìgbà tàbí àkókò tí wọ́n máa ṣí i.
Kókó ẹ̀sun tí wọ́n fi kan àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ redio ọ̀hún ni pé wọ́n sọ̀rọ̀ ta ko bí ṣọja ṣe dìtẹ̀-gbàjọba lọ́wọ́ Ààrẹ orílẹ̀-èdè Niger, Mohammed Bazoum lóṣù tó kọjá yìí.
Oun tí a gbọ́ ni pé ileeṣẹ redio ọ̀hún gba Ọgbẹni Ousmane Abdul Moumoni, ti i ṣe agbẹnusọ ẹgbẹ́ aladaani kan tó ń ta ko bi ṣọja ṣe ditẹ-gbajọba lọwọ aarẹ alagbada orile-ede Niger lalejo. Lasiko ifọrọwero to waye laarin awọn ati alejo naa ni Ọgbẹni Moumouni sọ oniruuru ọrọ to tabuku ba awọn ṣọja naa.
Loju-ẹsẹ tí ìròyìn ọhun de etiigbo mínísítà ètò ìròyìn nilẹ Burkina Faso, Ọgbẹni Rimtalba Jean Emmanuel Ouedraogo, lo ti kede pe ijọba ilẹ Burkina Faso ti fofin de ileeṣẹ naa, o si gbọdọ wa ni titi pa titi di akoko ti wọn maa fi ṣewadii lori ohun to fa a ti alejo ileeṣẹ redio ọhun ṣe bu ẹnu atẹ lu awọn alaṣẹ ilẹ Niger lori afẹfẹ.
Mínísítà yìí ní ẹgbẹ́ aladaani àti àlejò tí wọ́n gbà lórí ètò wọn ń ṣiṣẹ́ labẹnu láti da ogun abẹle silẹ lorileede naa ni, ati pe awọn ọrọ alufanṣa gbogbo to n sọ lẹnu lori afẹfẹ lọjọ naa le fa wahala nla silẹ laarin ilu Niger.
Ó ní kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé inú wàhàlà làwọn kan ti n jẹun. Irú ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àlejò tí wọ́n gbà lórí rédíò yìí lọ́jọ́ náà wà’.