Ilẹ̀ Russia fohùn léde fún ECOWAS lórì ídìtẹ̀gbàjọba Niger

Ilẹ̀ Russia fohùn léde fún ECOWAS lórì ídìtẹ̀gbàjọba Niger

Fẹ́mi Akínṣọlá

Látàrí awuyewuye tó bẹ́ sílẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdìtẹ̀-gbàjọba tó wáyé lórílẹ̀-èdè alámùúlétì wa, Niger, àti ìpinnu àjọ àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Africa ti wọ́n ń ṣe ẹgbẹ́ Economic Community of West African States, ECOWAS, láti gbé ìgbéṣẹ̀ ológun lòdì sáwọn ṣọ́jà tí wọ́n gbàjọba Niger ọ̀hún, orílẹ-èdè Russia ti bẹ̀rẹ̀ sí í laago ìkìlọ̀ fún àjọ ECOWAS àti Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu létí pé kí wọ́n máṣe dán an wò pé àwọn yóó lọ kógun ja àwọn adìtẹ̀-gbàjọba ilẹ̀ Niger ọ̀hún, wọ́n ní àbájáde rẹ̀ kò ní í sèso rere kan fún gbogbo agbègbè ilẹ̀ Sahara àti Sahel èyí tí ọ̀pọ̀ orílẹ-èdè wà, títí kan Nigeria àti Niger.

Nínú àtẹ̀jáde kan, tí àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè lórílẹ̀-èdè Rọsia ọ̀hún fi léde, nípa lọgbọ-lọgbọ tó ń ṣẹlẹ̀ nilẹ Niger, níbẹ̀ ni wọ́n ti ṣekilọ pé wàhálà tí kò ní í tán bọ̀rọ̀, tó sì lè di egbò àdáàjiná ni yóò tìdí rẹ̀ yọ, tí àjọ ECOWAS bá fi ṣàkọlù sí ìjọba ilẹ̀ Niger. Wọ́n ní níṣe nirú ìgbésẹ ológun bẹ́ẹ̀ yóó dabarú gbogbo nǹkan lágbègbè ọ̀hún.

Àtẹ̀jáde náà kà lápákan pé: “ Ilẹ̀ Russia gbàgbọ́ pé lílọ lógun ja ilẹ̀ Niger lè ṣokùnfà ìjà àti ọ̀tẹ̀ tí kò ní í tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀ lórílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfríkà náà, yóò sì mú kí ìpínyà àti àìfararọ wáyé jàkè jádò gbogbo ilẹ̀ Sahara àti Sahel lódidi.”

Lásàálẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlá, oṣù Kẹjọ yìí, ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú Niger bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ńlá kan ta ko ìpinnu ECOWAS láti fipá lé àwọn ṣọ́jà kúrò lórí àlééfà.

Àwọn èrò rẹpẹtẹ náà bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin òwe àti ọ̀tẹ̀ lòdì sí àjọ ECOWAS àti ilẹ̀ France, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ wọn kó àsìá ilẹ̀ Russia lọ́wọ́ ya-yaa-ya, wọ́n ní inú àwọn dùn sí báwọn ológun ilẹ̀ àwọn ṣe lé Ààrẹ Mohamed Bazoun kúrò nípò, wọ́n sì láwọn o ò fara mọ́ àrọwà àti ìgbésẹ ìpadàsípò kankan fún ọkùnrin Ààrẹ wọn tẹ́lẹ̀rí ọ̀hún, èyí tí ECOWAS sọ fáwọn ológun Niger pé kí wọ́n ṣe.

Ẹ ó rántí pé Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kẹjọ yìí, ni àjọ ECOWAS tún ṣèpàdé kejì láàrin ọjọ́ mẹwàá, ìpàdé ọhún kò sì dá lérí oun méjì ju ọ̀rọ̀ ìgbàjọba nílẹ̀ èNiger ọ̀hún lọ. ECOWAS pàṣẹ pé káwọn
sọ́jà ti ikọ̀ ECOWAS lọ bẹ̀rẹ̀ sí í tamọ́ra, kí wọ́n sì máa gbaradì lójúnà àti lé àwọn adìtẹ̀-gbàjọba ilẹ̀ Niger ọ̀hún lọ, kí wọ́n sì dá ìjọba olóṣèlú tí Bazoum ń tukọ rẹ̀ tẹlẹ, padà, ìyẹn bí àwọn ṣọ́jà náà kò bá gbà lẹ́rọ̀, pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ a àjọsọ, i ìpàrọwà àti ìfikùn lukùn táwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ rẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here