Ìdàgbàsókè tó pọ̀ yóò dé bá ojúbọ Ọ̀ṣun Osogbo ní ìwòyí ọdún tó ń bọ̀ – Adeleke

Ìdàgbàsókè tó pọ̀ yóò dé bá ojúbọ Ọ̀ṣun Osogbo ní ìwòyí ọdún tó ń bọ̀ – Adeleke

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní èèyàn tó mojú ògún ní-ín pabì nírè.
Ilu Osogbo ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun mi títí pẹ̀lú bí àwọn ónìṣese káàkiri àgbáyé ṣe péjú pésẹ̀ láti se ayẹyẹ àsekágbá ọdún Ọ̀ṣun Osogbo ti ọdún yìí.

Ataoja tí ìlú Osogbo, Ọba Jimoh Oyetunji Olanipekun àti àwọn olorí, ìjòyè àti àwọn ará ìlú gbogbo ló péjú síbi ayẹyẹ Ọdún náà.

Ataoja tí ìlú Osogbo nínú ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ ní àkókò tí ọdún Ọ̀ṣun Osogbo dùn jù ni ti ọdún yìí pẹ̀lú bí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀sun se lọ́wọ́ sí ètò gbogbo, tí wọ́n sì ṣe àdúrà fún onílé àti àlejò.

Gómìnà Ademola Adeleke àti ìyàwó rẹ̀ náà kò gbẹ́yìn níbi ayẹyẹ ọ̀hún pẹ̀lú gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀.

Gómìnà Ademola ni ìdàgbàsókè tó pọ̀ yóò dé bá ojúbọ Ọ̀ṣun Osogbo àti ayẹyẹ ọdún náà pẹ̀lú àwọn nǹkan mèremère tí ìjọba túbọ máa se láti gbé àṣà lárugẹ.

Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò, Iba Gani Adams gbóríyìn fún ìjọba Ademola Adeleke fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ̀ lórí ayẹyẹ Ọdún Ọ̀ṣun Osogbo tó mú kí tí
ó yàtò.

Gani Adams tún kìlọ̀ fún àwọn aṣẹ̀bàjé tí wọ́n má ń lo àkókò ayẹyẹ ọdún náà láti ja àwọn àlejò àti onílé lólè láti dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ náà.

Ó ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Oòduà Peoples Congress, OPC, yóò ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn elétò àbọ̀ tó kú ní ọdún tó ń bọ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here