Nínú ibojì òkú yìí làwa ti ń jẹun, sùn, ṣiṣẹ́, ẹ ṣàánú wa torí …

Nínú ibojì òkú yìí làwa ti ń jẹun, sùn, ṣiṣẹ́, ẹ ṣàánú wa torí …

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní àìrìnjìnà làì rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́. Bí ẹ bá
gbọ́ tẹnu ẹlòmí-ìn ,bí èyì n kọ́?
“A ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí nínú ibojì yìí ju nínú ilé wa gangan lọ, bí a bá sì fẹ́ jẹun, a máa ń lo àwọn pálí táa fi sin àwọn òkú láti jókòó jẹun tàbí dùbúlẹ̀ tí a bá fẹ́ sùn”.

Ní ààrin gbùngbùn ibojì òkú ńlá tó wà ní ìlú yìí, ó ní àwọn géńdé ọkùnrin kan tí wọ́n ti fi ayé wọn jì fún ṣíṣe iṣẹ́ níbẹ̀.

Awọn ọkunrin yii to bii mẹtadinlogun ti wọn si maa n gbẹ ilẹ ibi itẹ, awọn kan naa lo maa n ba awọn eeyan sin oku bẹẹ si ni awọn ni wọn n gba ilẹ, ṣe itọju iboji okun Tundun Wada to wa ni ipinlẹ Kaduna lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Abdulwahid Abdulsalam to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọta jẹ ọkan lara wọn, o si sọ fun BBC pe oun ti ṣiṣẹ fun ọdun mẹẹdọgbọn bayii ti inu iboji oku si ti di ile oun.

Awọn oṣiṣẹ iboji oku
Abdulwahid ni ago meje abọ owurọ loun maa n fi ile oun silẹ lojoojumọ lati lọ bẹrẹ iṣẹ titi di alẹ si oun yoo to pada sile.

“Igba miran ti a ba ti pari iṣẹ lalẹ, awọn mii le pe wa wipe awọn fẹ gbe oku wa, bẹẹ si ni a o pa lilọ sile ti ayafi bi a ba sin ẹni naa tan.”

O ṣalaye pe iṣẹ yii jẹ iṣẹ ti awọn n ṣe lai ni ojulowo adehun iye owo oṣu wọn latọdọ ijọba ṣugbọn awọn ṣi n ṣe e lati gba ere lati ọrun wa.

“Idi ti a fi n ṣe iṣẹ yii ni pe ibi yii ni ibi isinmi ikẹhin fun gbogbo eniyan, a si tun n ṣe e nitori Ọlọrun.”

“Mo ni awọn mọlẹbi ti a sin sibi ati pe o ṣe e ṣe gan ko jẹ pe ibi yii naa ni wọn maa sin emi naa si nitorinaa, eleyi jẹ iṣẹ isin fun ara mi gan.”

“Nigba miran, lẹyin isinku, a o kan ṣi fila ori wa lati fi tọrọ agbe lọwọ awọn to wa lati sin oku lara eyi si la ti n fi bọ ara wa ati idile wa.”
Akẹgbẹ rẹ to tun jẹ ọga fun un lẹnu iṣẹ, Abdulaziz Ibrahim bẹrẹ iṣẹ yii ni ọdun mọkanlolọgbọn sẹyin o si sọrọ pe bi oun ṣe fi aye oun ji fun iṣẹ naa mu ki o wu oun bi ikankan ninu awọn mọ oun yoo ba le tọ ipasẹ oun.

“Inu mi yoo dun ki ọkan lara awọn ọmọ mi to ba fẹ ko ṣe iṣẹ yi toripe ohun to dara ni fun igbẹyin wọn”.

Abdulaziz ni wọn baba oun ati aburo baba oun sibẹ ti oun si maa n lọ bẹ oroori wọn wo lati gbadura fun wọn.

“nibi ni awọn naa ti ṣiṣẹ ki wọn to ku koda baba mi gan maa n wa ṣiṣẹ lasiko to ni ijamba kan lẹnu ibode ibi eyi to ja si iku rẹ.”

Awọn oṣiṣẹ iboji wa ke si ijọba atawọn ọlọdani lati nawọ iranwọ si wọn paapaa bo ṣe jẹ pe pupọ ninu irinṣẹ ti wọn n lo ni wọn maa n ya.

“Koda, sọburu ati diga yii, a maa n ya a wa sibi iṣẹ nitorinaa, a nilo iranlọwọ gidi lati le tẹsiwaju ninu iṣẹ yii.”

“Ilana yii ni a maa n gba sin ẹni to ba ti ku”
Gẹgẹ bi Abdulwahid ṣe ṣalaye, bi wọn ba ti gba ipe pe eeyan kan ku, wọn yoo tete bẹrẹ iṣẹ.

“Ohun akọkọ ni pe ẹni naa gbudọ jẹ musulumi niwọn igba to ti jẹ wipe iboji oki fun awọn musulumi ni eleyi lẹyin naa, a o bere lọwọ eeyan to pe wa lati sọ nipa iku ẹni naa fun wa lati bere boya oku naa jẹ ẹni to sanra tabi tiinrin”.

“Idi ti a fi maa n bere bi oku naa ṣe sanra si ati giga rẹ ni pe bi gbogbo eniyan ṣe yatọ naa ni oroori wọn naa yoo ṣe yatọ”.

O ni: “iṣẹ temi ni lati rii pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ nigba ti wọn ba si gbe oku naa de, a o gbe e sinu iboji.”

‘Fiimu ló máa ń tan àwọn èèyàn nípa àwọn oku’
Abdulaziz sọ pé kò sí nǹkan tó ń jẹ́ wípé oku ń wà láyé bí àwọn fíìmù ṣe máa ń ṣe àpèjúwe wọn, ó ní igbakiigba tí òun bá rí i òun kàn máa ń rẹrin ni.

“Ninu fíìmù, nígbà mìíràn ẹ o máa rí i ti òkú yóò máa lé ènìyàn, itanjẹ lásán ni gbogbo ẹ nítorípé lójú ayé gangan, kò sí nǹkan tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.

“Mo ti ń ṣiṣẹ́ níbi láti Oṣù Keje ọdún 1992 mi ò sì tíì gbọ ìròyìn kankan tàbí rí nkànkan tó leè mú mi bẹru.”

Abdulaziz ni ọjọ́ kan tí òun kò le láyé láyé gbàgbé ni ọjọ́ tí ìjàǹbá pa èèyàn mejidinlogun tán yan-an-yan tí wọ́n ń rinrinajo tí wọ́n wá gbé oku gbogbo wọn wá sí ibojì òkú àwọn.

“Ó jẹ́ ọjọ́ tí mi ò le gbàgbé láyé lẹnu iṣẹ́ yìí. Ọjọ yẹn jẹ́ ọjọ́ aburú pẹlú bí àwọn obìnrin àti ọmọdé gan ṣe tún wà lára àwọn tó kú.”

Abdulwahid àti Abdulaziz ní yóò wu àwọn kí àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn sin òkú àwọn sí ibojì Tundun Wadda lẹ́yìn tí àwọn bá dágbére fáyé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe lára àwọn mọ̀lẹ́bí wọn kan tí wọ́n ti sin síb.ẹ̀

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here