“Iléeṣẹ́ tí wọ́n ti n fọ epo ní Port Harcourt yóó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú oṣù Kejìlá”

“Iléeṣẹ́ tí wọ́n ti n fọ epo ní Port Harcourt yóó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú oṣù Kejìlá”

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ààrẹ Nàìjíríà, Bọla Tinubu ti ṣèlérí láti parí àtúnṣe iléeṣẹ́ ìfọpo tó wà nílùú Portharcourt kí ọdún 2023 tó parí.

Eyi jẹyọ lẹyin ti ipade waye laarin aarẹ atawọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria.

Agbenusọ Tinubu, Dele Alake lo fi ọrọ naa lede lẹyin ipade bonkẹlẹ naa to waye niluu Abuja.

Alake fi kun pe Aarẹ Tinubu ṣeleri fun awọn adari oṣiṣẹ ọhun pe ijọba yoo ṣatunṣe ileeṣẹ ti wọn ti n fọ epo to wa niluu Port Harcourt, yoo si bẹrẹ iṣẹ ninu oṣu Kejila, ọdun 2023 yii.

Amọ ko tii si ẹni lee sọ boya eyi yoo to fun awọn oṣiṣẹ ni idaniloju ati ṣẹwele iyanṣẹlodi wọn.

Alake sọ pé “lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe pẹ̀lú Ààrẹ àti ìgbàgbọ́ wọn nínú rẹ̀ pé yóó ṣe àgbéyẹ̀wó àwọn ohun tí wọn gbé wá síwájú rẹ̀, wọ́n ti gbà láti wá ọ̀nà míì láti jíròrò pẹ̀lú ìjọba lórí àwọn ohun tí wọ́n n bèèrè láti ọjọ́ pípẹ́ wá.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here