Ẹgbẹ́ PDP gba àwọn alákòóso Mákindé tuntun nímọ̀ràn

Ẹgbẹ́ PDP gba àwọn alákòóso Mákindé tuntun nímọ̀ràn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àmọ̀ràn ti lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò níṣèjọba sáà kejì Ẹnjinníà Ṣeyì Mákindé láti gbájú mọ́ṣẹ́ ìlú.Ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP), ní ìpínlẹ̀ Ọyọ , ló gba àwọn ẹni ọ̀rọ̀ kàn ọ̀hún, akọ̀wé ìjọba, olórí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì Gómìnà àtàwọn kọmíṣánnà láti fìmọ̀ ṣọ̀kan, kí wọ́n sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Gómìnà láti mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Adelé Alukoro fún ẹgbẹ́ náà, Micheal Ogunṣina, ló gbà wọ́n nímọ̀ràn yìí nínú atẹjade tó fi ṣọwọ́ sáwọn oníròyìn l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù Keje, ọdún 2023 yìí.

Bákan náà ló kí akọ̀wé ìjọba tuntun, àtàwọn kọmísánnà mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún (16), olùṣirò owó àgbà tuntun, àti àwọn akọ̀wé ìjọba tí Gómìnà Ṣeyi Mákindé ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù yìí.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, ó ní, “a gbàgbọ́ nínú àwọn èèyàn tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé yan yìí, nítorí àwọn ipa rere tí wọ́n ti ko nínú iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò.

Àwọn ipa tí wọ́n ti ko tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé-iṣẹ́ káàkiri ti fihàn pé wọ́n yóò wúlò fún àfojúsùn Gómìnà fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

‘ Gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ PDP ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, a rọ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn yìí láti má fi iṣẹ́ wọn tàfàlà, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ takuntakun fún ìgbélárugẹ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́”.

Ẹgbẹ́ PDP ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ jẹjẹẹ láti fọwọsowọpọ pẹ̀lú akọwe ìjọba tuntun, àwọn kọmísánnà, olùṣirò owó àgbà, àtàwọn akọ̀wé àgbà tuntun yìí, kí ìpínlẹ̀ yìí lè gòkè àgbà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here