Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá sọsẹ́ n’Íbàdàn, ọ̀pọ̀ dúkìá sòfò

Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá sọsẹ́ n’Íbàdàn, ọ̀pọ̀ dúkìá sòfò

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ogunlọ́gọ̀ dúkìá olówó iyebíye làgbàrá òjò wọ́ lọ níjọba ìbílẹ̀ Ido, n’Íbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, lẹ́yìn tí arọọda ojo kan rọ lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlélógùn, oṣù Keje, ọdún 2023 yìí.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjànbá lòjò alágbára yìí ṣe fún àwọn èèyàn abúlé níbẹ̀, tó sì ba ètò ọrọ̀ ajé wọn jẹ́.

Lara awọn adugbo to fara gba ninu ijamba omiyale naa ni: Ọmi Adio, Apata ati ilu Ido funra ẹ.

Akọ̀ròyìn wa gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀bù àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lojo yii wọ lọ lọja Ọmi Adio, koda, alagbalugbu agbara ojo naa tun wọ ọpọlọpọ odo ẹja lọ lagbegbe naa, o si wọ awọn ẹja ti wọn n sin ninu wọn lọ.

Ọgbẹni Festus Adeṣina, ọkan ninu awọn agbẹ to fara gba ninu iṣẹlẹ yii, ṣalaye pe ko din ni ọgọrin (80) odo ẹja ti omi gbe lọ.

Ó ní bíi mílíọ̀nù mẹwàá Náírà lòun fi ń ṣe okoòwò òun, ṣùgbọ́n níṣe lomi gbe gbogbo rẹ̀ lọ pátápátá.

Obìnrin oníṣòwò kan tóun náà fara gbá nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Alaaja Alimot Adeleke, rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti dìde ìrànwọ́ fóun àti ẹni gbogbo tó kàgbákò ẹ̀kún omi náà.

Adeleke ni ọpọlọpọ baagi gaari, ẹgẹ ati apo ounjẹ lo ba iṣẹlẹ ọhun rin.

Ó fi kún un pé ṣọ́ọ̀bù yìí lòun fi ń gbọ bùkáátà àwọn ọmọ òun látìgbà tóun ti pàdánù ọkọ òun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here