Kìí ṣe nítorí Yari kọ̀ láti gbé ìpè Tinubu là ṣe ránṣẹ́ pè é – DSS

Kìí ṣe nítorí Yari kọ̀ láti gbé ìpè Tinubu là ṣe ránṣẹ́ pè é – DSS

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ẹ̀là lọ̀rọ̀, bí a kò bá làá, kìí yéni. Iléeṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS ti jiyàn ìròyìn pé àwọn ránṣẹ́ pé aṣòfin tó ń ṣojú ẹkùn iwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Zamfara nílé aṣòfin àgbà, Abdulaziz Yari nítorí pé ó kọ̀ láti gbé ìpè Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.

Àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ DSS, Peter Afunanya fi síta lọ́jọ́ Àìkú ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ Afunanya kò sọ ìdí tí àjọ náà fi fọ̀rọ̀ wá Yari lẹ́nu wò, irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ látọwọ́ Iléeṣẹ́ ìròyìn ṣàfihàn bí àwọn kan ṣe ń tàbùkù iṣẹ́ ìròyìn.

Ó ní ohun tó dájú ni pé Yari, tó ti fìgbà kan jẹ́ gómìnà ní ìpínlẹ̀ Zamfara fúnra rẹ̀ mọ ìdí tí àwọn fi ránṣẹ́ pé òun.

Ó ṣàlàyé pé tí àjọ àwọn bá nílò láti ránṣẹ́ pé ẹnìkan tàbí fi èèyàn kan sí àhámọ́ àwọn kò ní kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ níwọ̀nba ìgbà tí àwọn bá ti tẹ̀lé ìlànà tí òfin là kalẹ̀.

Bákan náà ni Afunanya tún jiyàn àwọn ìròyìn pé àwọn lọ yawọ ọ́fíìsì àjọ ICPC àti CCB tí àwọn sì kó àwọn fáìlì níbẹ̀.

Afunanya fi kun pé láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, àwọn kò lọ sí ICPC tàbí CCB láti lọ kó fáìlì kankan.

Ó ní ìròyìn elẹ́jẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ tó sì rọ àwọn akọ̀ròyìn láti máa ṣe ìwádìí wọn dáadáa kí wọ́n tó máa gbé ìròyìn.

Ó fẹnu ọ̀rọ̀ tì pé Iléeṣẹ́ àwọn kò ní jẹ́ kí ìròyìn elẹ́jẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn láti ṣe ojúṣe àwọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here