Tinubu balẹ̀ sí Guinea-Bissau fún àpérò àjọ ECOWAS
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ààrẹ Orílẹ̀ yìí, Bola Ahmed Tinubu ti gúnlẹ̀ sí orílẹ̀ èdè Guinea-Bissau láti kópa níbi àpérò àwọn olórí orílẹ̀ èdè àjọ ECOWAS.
Agbẹnusọ Ààrẹ, Dele Alake nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní Tinubu máa lò àkókò yìí láti fi sáwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tó wà ní Guinea-Bissau.
Ó ní àpérò yìí tó jẹ́ ẹlẹ́kẹtàlélọ́gọ́ta irú rẹ̀ ni àpérò ilẹ̀ Adúláwò àkọ́kọ́ tí Tinubu yóò kópa níbẹ̀ láti ìgbà tó ti dé ipò Ààrẹ.
Ó ṣàlàyé pé àwọn olórí orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlógún ni ìrètí wà pé wọ́n máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tó ń bá ilẹ̀ Adúláwọ̀ fínra pàápàá lórí ètò ààbò.
Bákan náà ló ní wọ́n tún máa jíròrò lórí bí àwọn alágbádá ṣe máa gba ìjọba padà ní orílẹ̀ èdè Mali, Burkina Faso àti Guinea, ìṣàmúlò owó ẹyọ kan ṣoṣo láàárín àwọn orílẹ̀ èdè àjọ ECOWAS àti ìdènà tó ń bá ọjà rírà àti títà láàárín Èkó àti Abidjan.
Nígbà tó ń bá àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tó wà ní Guinea-Bissau sọ̀rọ̀, Ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá wọn iṣẹ́ ìsìn wọn sí Nàìjíríà àti orílẹ̀ èdè tí wọ́n wà.
ÀàrẹTinubu ní ìrètí wà pé yóò tún ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè kan kí okùn ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀ èdè le yi dain fún ìtèsíwájú.