Ilé aṣòfin Osun gbórúkọ àwọn Kọmíṣọ́nà tuntun síta

Ilé aṣòfin Osun gbórúkọ àwọn Kọmíṣọ́nà tuntun síta

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní bí àwọn èèyàn kan ṣe n gbée pòòyì ẹnu pé ó ti yẹ kí gómìnà Ademola Adeleke kọ orúkọ àwọn tófẹ́ yàn sípò kọmíṣọ́nà jáde, ní báyìí, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun ti ṣe àgbéjáde àwọn orúkọ ènìyàn tí gómìnà Ademola Adeleke kọ ránṣẹ́ sí pé kí wọ́n dipò kọmíṣọ́nà àti àwọn olùbádámọ̀ràn ní ìpínlẹ̀ náà mú.

Níbi ìjókòó ilé ní ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Keje oṣù Keje ni Abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun, Adewale Egbedun ti ka lẹ́tà kan tí orúkọ àwọn ènìyàn náà èyí tí gómìnà Adeleke kọ ránṣẹ́ sí etí gbogbo àwọn ọmọ ilé.

Egbedun ní àwọn máa ṣe àgbédìde ìgbìmọ̀ tó máa kọ́kọ́ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ náà ní abẹ́nú kí ilé tó tún wá ṣe ìdánwò fún wọ́n kí wọ́n tó buwọ́lù wọ́n.

Lára àwọn orúkọ tó wà nínú lẹ́tà gómìnà náà ni Agbẹjọ́rò Oladosu Babatunde, Ọmọọba Bayo Ogungbangbe, Sesan Epharaim Oyedele, Agbẹjọ́rò Kolapo Alimi, Soji Ajeigbe, Moshood Olalekan Olagunju, George Alabi, Sunday Olufemi Oroniyi, Abiodun Bankole Ojo, àti Dókítà Basiru Tokunbo Salami.

Àwọn mìíràn ni Morufu Ayofe, Sola Ogungbile, Ẹni ọ̀wọ̀ Bunmi Jenyo, Ayo Awolowo, Agbẹjọ́rò Wole Jimi Bada, Dipo Eluwole, Alhaji Rasheed Aderibigbe, Ọ̀jọ̀gbọ́n Morufu Ademola Adeleke, Adeyemo Festus Ademola, Olabiyi Anthony Odunlade, Agbẹjọ́rò Jola Akintola, Mayowa Adejori, Adenike Folashade Adeleke, Tola Faseru, àti Alhaji Ganiyu Ayobami Olaoluwa.

Ilé aṣòfin náà ti wá gbé ìgbìmọ̀ tí yóò kọ́kọ́ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ náà kalẹ̀ tí wọ́n sì ní kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn ní kíákíá.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here