Iléèṣẹ́ ológun pàṣẹ kí àwọn ọ̀gágun kan kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀

Iléèṣẹ́ ológun pàṣẹ kí àwọn ọ̀gágun kan kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní bí ẹ̀ẹ̀kẹ́ ọmọ ẹranko kò bàjẹ́, ti ọmọ èèyàn kò le dùn.
Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀gá ológun tó ti kẹ́kọ̀ọ́ tayọ ìpele kọkàndínlógójì ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ ológun, láti kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ fúnra wọn.

Àṣẹ náà wáyé lẹ́yìn tí Ààrẹ Bola Tinubu yan àwọn ọ̀gá aláàbò tuntun.

Àwọn ọ̀ga náà jẹ́ ọ̀gá fún àwọn olórí iléeṣẹ́ ológun ti Ààrẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn.

Ìkéde náà wáyé nínú àtẹ̀jáde kan tí Major General Y. Yahaya fi síta ní orúkọ ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà.

Ó ní ní kíákíá ni kí gbogbo àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ tayọ ìpele k kọkàndínlógójì kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀.

“Gbogbo àwọn ọ̀gágun tí ọ̀rọ̀ kàn gbọdọ̀ fi ìwé wọn ránṣẹ́ sí iléeṣẹ́ ológun, ó pẹ́ jù, ọjọ́ kẹta, oṣù Keje, ọdún 2023.”

Irú àṣẹ yìí kò jẹ́ tuntun. Ìdí ni pé lára àṣà iléeṣẹ́ ológun ni pé àwọn ọ̀gágun kìí lè gba àṣẹ lọ́wọ́ ọmọ abẹ́ wọn tó bá di ọ̀gá àgbà ológun.

Nítorí èyí, kò dín ní ọgọ́ọ̀rún ọ̀gágun tí ìyànsípò ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun tuntun yóò fi tipátipá mú kọ̀wé fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀.

Àwọn General, Brigadier General, Air Vice Marshals àti Admirals ni àṣẹ náà kan níléeṣẹ́ ológun orí ilẹ̀, orí omi àti ti òfurufú.

Ìpele kejìdínlógún ni olórí aláàbò tuntun, Major General Christopher Musa wà, nígbà tí olórí iléeṣẹ́ ológun orí ilẹ̀, Major General Taoreed Lagbaja, ọgá àgbà ọmọ ogun orí omi, Rear Admiral Emmanuel Ogalla, àti Air Vice Marshal Hassan Abubakar tó jẹ́ ọ̀gá tuntun níléeṣẹ́ ológun òfurufú, wà ní ìpele kọkàndínlógójì

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here