Ká ní mo lulẹ̀ ìbò Sẹ́nétọ̀ ni – Oshiomole

Kání mo lulẹ̀ ìbò Sẹ́nétọ̀ ni……– Oshiomole

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò sí èèyàn tíí tan mọ́ ẹbí aláṣetì, aláseyọrí ni gbogbo ayé bá tan.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo nígbà kan rí, Adams Oshiomole ti sọ pé òun kò bá ti ní ẹ̀jẹ̀ ríru tó bá jẹ́ pé òun lulẹ̀ nínú ìdìbò sípò Sẹ́nétọ̀ tó wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.

Oshiomole ló sọ ọ̀rọ̀ náà níbi wẹ̀jẹ-wẹ̀mu kan tí àwọn ọ̀rẹ́ àti olólùfẹ́ rẹ̀ kan ṣe fun ní ìlú Iyamho, Etsako, níìpínlẹ̀ Edo.

Gómìnà tó ṣèjọba lẹ́yìn Oshiomole, Godwin Obaseki ni wọ́n jọ du ipò Sẹ́nétọ̀náà àmọ́ ó já mọ́ Oshiomole lọ́wọ́.

Ó ní “ tó bá jẹ́ pé ẹ kò dìbò fún mi ni, ẹ̀jẹ̀ mi yóó ti ru sí 240/ 360, ìyẹn tí mo bá ṣì wà láàyè. ”

Gẹ́gẹ́ bíi ohun tó sọ, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti ṣe Gómìnà tí wọ́n sì kùnà láti di Sẹ́nétọ̀ lẹ́yìn sáà wọn àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ fún òun, yóò sì jẹ́ ohun itìjú tí òun bá lulẹ̀.

Lẹ́yìn náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Edo pé wọ́n fi ìbò wọn gbé òun wọlé gẹ́gẹ́ bíi Sẹ́nétọ̀ lẹ́yìn tó ṣe Gómìnà tán.

Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn ọ̀hún fún àtìlẹ́yìn wọn fún Ààrẹ Nàìjíríà tuntun, Aṣíwájú Bola Tinubu lásìkò ètò ìdìbò tó kọjá.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here