Kí ẹ ṣọ́ra fún mímu “Sprite 50cl” lásíkò yìí, a rí àbàwọ́n nínú rẹ̀ – NAFDAC

Kí ẹ ṣọ́ra fún mímu “Sprite 50cl” lásíkò yìí, a rí àbàwọ́n nínú rẹ̀ – NAFDAC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó ń gbógun ti àṣìlò oògùn àti ìdáàbòbò oúnjẹ fún àwọn aráàlú, NAFDAC ti késí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ṣọ́ra fún mímu ohun ẹlẹ́rìndòdò “Sprite 50cl” tó ń káàkiri ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

NAFDAC ní ohun ẹlẹ́rìndòdò náà ni àwọn ríi pé ó ti ní àbàwọn lẹ́yìn tí oníbàárà kan fi ẹ̀sùn kan, tí àwọn sì sèwádìí ẹ̀sùn ọ̀hún.

Àjọ náà ní ìwádìí àwọn fihàn pé crate tó lé ní márùn ún nínú Sprite 50cl tí wọ́n kó jáde nígbà náà ni ó ní ìdọ̀tí nínú.

A ti sèwádìí àwọn eléyìí tí kò dára níbẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ wa ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àbàbwọ́n wà nínú àwọn kọ̀ọ̀kan.

Bákan náà ni wọn fikún un pé awọn ti késí awọn adarí ní ipinlẹ kọ̀ọ̀kan láti se àyẹ̀wò àwọn “Sprite 50cl” tó wà ní agbègbè wọn.

NAFDAC kéde pé àwọn ti késí iléeṣẹ́ “Coca -Cola” láti kíyèsí iye ti iléeṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ Abuja Plant pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ AZ6 22:32.

Ó fikún un Ọjọ́ Kẹta, Oṣù Kẹrin ọdún yìí ni wọ́n se àwọn “Bitter Lemon” tó ní àbàwọ́n náà.

NAFDAC wá késí àwọn ọlọ́jà àti oníbàárà láti se sùúrù , kí wọ́n sì wò ó fínífíní kí wọ́n tó mu ún Sprite.

‘’Ẹ gbọ́dọ̀o yẹ ara rẹ̀ wò dáradára, kí ẹ rí i pé kìí se eléyìí tí kò dára.

Bákan náà ni wọ́n késí ẹni tó bá ni eléyìí tí kò dára yìí lọ́wọ́ , kí ó gbé e lọ sí iléesẹ́ àjọ NAFDAC tó bá sún mọ́ wọn.

Àjọ NAFDAC wá rọ àwọn aráàlú tí wọ́n bá ti mu Sprite yìí, tí ó sì ti gbòdì lára wọn, kí wọ́n lọ sí iléwòsàn fún ìtọ́jú tó péye.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here