Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ 5,344.1Kg igbó nípìńlẹ̀ Èkó

Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ 5,344.1Kg igbó nípìńlẹ̀ Èkó
Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ṣoṣo ni ti olóhun bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ dà bí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń gbógun ti lílò òògùn olóró ní Nàìjíríà, NDLEA, ti gbẹ́sẹ̀ lé igbó tí òdinwọ̀n rẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún kílógíráámù, 5, 344.1Kg nípìńlẹ̀ Èkó.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ àjọ náà, Femi Babafemi fi síta, ó ní ọwọ́ tẹ òògùn olóró náà lẹ́yìn tí ìròyìn tẹ àjọ NDLEA lọ́wọ́ pe ọkọ̀ akẹ́rù kan yóò gba agbègbè Alpha Beach, lójú ọ̀nà Epe sí Lekki kọjá.

“ Àwọn òṣìṣẹ́ NDLEA dènà de ọkọ̀ tó kó òògùn olóró tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 2434.1kg, tí wọ́n dì sínú àádọta àpo, ní òwúrọ̀ kutu ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kọkandin lógún, oṣù Kẹfà.”

Ṣùgbọ́n awakọ̀ rẹ̀ fò jáde nínú ọkọ̀ tó sì sáré kó sínú ọkọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò tó ń bá rinrinajo .

Yàtọ̀ sí èyí, Ọgbẹni Babafẹmi sọ pé ọwọ́ tún tẹ àwọn ọkùnrin méjì kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ghana ní ogúnjọ́ oṣù Kẹfà bákan náà, níbi tí wọ́n ti wà pẹ̀lú ìwọn 2,910kg igbó ní Alpha Beach.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here