Kí ẹgbẹ́ APC le wọlé ìbò ni Buhari kò ṣe yọ ‘subsidy’ – Garba Shehu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ọ̀rọ̀ tó bá dánilójú, kìí kọsẹ̀ létè ẹni.
Agbẹnusọ Ààrẹ àná Nàìjíríà, Garba Shehu ti ṣàlàyé ìdí tí Muhammadu Buhari kò ṣe yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù nígbà tó wà nípò.
Garba Shehu ní Buhari kọ̀ láti yọ ìrànwọ́ orí epo nítorí pé kò ì tíì tó àkókò tó yẹ kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó kúrò lórí ipò.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Shehu fi síta lọ́jọ́ Ajé ní ìjọba Muhammadu Buhari mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe ìdádúró yíyọ ìrànwọ́ orí epo náà fún àsìkò tó yẹ ni.
Ó ní irú ìgbésẹ̀ yìí kò lè wáyé lásìkò tí gbogbo nǹkan ń gbóná ní Nàìjíríà àti pé olórí rere kò ní hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.
Agbẹnusọ Ààrẹ àná náà ní ìjọba tuntun tó mọ nǹkan tó ń ṣe, tó sì ní ẹ̀mí láti ṣe dáadáa fún àwọn ará ìlú nìkan ló le gbé ìgbésẹ̀ tí Tinubu gbé.
Ó fi kun pé lára ìdí tí Buhari kò fi yọ ìrànwọ́ orí epo lásìkò tó ti fẹ́ gbé ìjọba sílẹ̀ ni láti ri pé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) jáwé olúborí ìbò Ààrẹ.
Ó ní àwọn ọmọ Nàìjíríà kò ní dìbò fún APC tó bá jẹ́ wí pé Buhari ti yọ ìrànwọ́ orí epo náà bí ètò ìdìbò ṣe ń bọ̀ lọ́nà.
“Nígbà tí a ti dìbò tán, olórí tó bá mọ ohun tó ń ṣe gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà láti tẹ̀síwájú.”
“Mo ní ìgboyà nínú ìjọba tuntun yìí pé wọ́n máa ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ètò lọ́kan-ò-jọ̀kan tó máa mú àyípadà rere bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.”
Bákan náà ló gbóríyìn fún Ààrẹ Tinubu àti igbákejì rẹ̀, Kashim Shettima fún yíyọ ìrànwọ́ orí epo àti ríri pé owó dọ́là jẹ́ bákan náà lọ́jà.
Shehu tún kan sáárá sí wọn pé wọ́n ṣe ètò náà dáadáa débi wí pé kò sí wàhálà kankan tó wáyé lẹ́yìn àwọn ìgbésẹ̀ yìí.
Ó tẹ̀síwájú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gá òun kò yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù, ó ní ọ̀pọ̀ ìrànwọ́ ni Buhari yọ bíi ti orí kẹrosíìnì, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó fi kun pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ìrànwọ́ tí Buhari yọ yìí ló ti máa ń ṣe àkóbá fún ètò ìsúná Nàìjíríà