Ileeṣẹ ti wọ́n ní k’awọn ọdẹ kan máa ṣọ ni wọ́n jà lólè

Ileeṣẹ ti wọ́n ní k’awọn ọdẹ kan máa ṣọ ni wọ́n jà lólè

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn ọdẹ mẹ́rin kan, Habila Anbeyi, ẹni ọdún mẹ́rìndílógún, Naruka Sababou, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ́n, Audi Ali, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ́n, àti John Danladi, ẹni ọgbọ̀n ọdún, ni adájọ́ ilé-ẹjọ́ kan ti wọ́n ń pè ní ‘Grade1 Area Court,’ tó wà nílùú Kabusa, l’Abuja, Onídàájọ́ Abubakar Sadiq, ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ̀ọ́ ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe.

Ohun tí a gbọ́ ni pé ileeṣẹ kan tó ń pèsè ààbò fawọn aráàlú, èyí tí wọ́n ń pè ní ‘Falzal Security Company’, to wa lagbegbe Wuse, nílùú Abuja, lawọn mẹrẹẹrin ọ̀hún ti ń ṣiṣẹ́. Níṣe ni wọ́n gbìmọ pọ̀ láti jí epo diisu ileeṣẹ náà ta fún àwọn aráàta.

Ọlọpaa olupẹjọ, Ọgbẹni S.O Osho, to foju awọn ọdaran naa han nile-ẹjọ sọ pe Akaaza Samuel, to jẹ ọkan lara awọn ọga agba ileeṣẹ ọhun lo lọọ fọrọ awọn odaran naa to ọlọpaa agbegbe Asokoro, niluu Abuja leti lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.

Agbefọba sọ pe, “Ẹyin mẹrẹẹrin yii, ẹ gbimọ-pọ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, tẹ ẹ si ji epo diisu ileeṣẹ tẹ ẹ ti n ṣiṣẹ. Igba lita (200lt) ti iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira lẹ ji gbe. Loju-ẹsẹ tẹ ẹ ti ji epo ọhun tan lẹ ti ta a fun ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Lawal lowo pọọku, ko too di pe, ọwọ awọn ọlọpaa tẹ yin.

“Loootọ, ẹ ti jẹwọ fawọn agbofinro lasiko ti wọn ni beere ọrọ lọwọ yin, ṣugbọn ijiya nla wa fun ohun tẹ ẹ ṣe yii labẹ ofin ilu yii”.

Bi ọlọpaa olupẹjọ ti ka awọn ẹṣẹ tawọn mẹrẹẹrin ṣẹ ṣi wọn lẹsẹ tan ni awọn paapaa ti gba pe loootọ lawọn jẹbi esun iwa ọdaran gbogbo ti wọn fi kan won pata, ti wọn si rawọ ẹbẹ si adajọ ile-ẹjọ naa pe ko ṣiju aanu wo awọn lori ọrọ to wa niwaju rẹ ọhun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Sadiq, ni ki ẹnikọọkan wọn lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa, tabi ki wọn san ẹgbẹrun lọna ogun naira gẹgẹ bii owo itanran.

Bakan naa ni adajọ ni ki ẹnikọọkan wọn tun san ẹgbẹrun lọna mẹẹẹdọgbọn Naira fun ileeṣẹ ti wọn ja lole naa gẹgẹ bíi owo gba-ma-binu fun dukia rẹ ti wọn ji.

Ó ní bí wọ́n bá kọ láti sanwó ọ̀hún, òun yóó fi oṣù méjì kún ọjọ́ tí wọ́n máa lò lọ́gbà ẹ̀wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here