Kò dájú pé Emefiele ò ní-ín sá kúrò ní Nàìjíríà tí ilé ẹjọ́ bá fún un ní béèlì – DSS

Kò dájú pé Emefiele ò ní-ín sá kúrò ní Nàìjíríà tí ilé ẹjọ́ bá fún un ní béèlì – DSS

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní kinní kan ló mẹsẹ̀ kinní kan tọ̀ lórí àpáta.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Nàìjíríà ìyẹn Department of State Services, DSS ti rọ ilé ẹjọ́ gíga ti ìlú Abuja láti da ẹjọ́ tí gómìnà tẹ́lẹ̀ fún ilé ìfowópamọ́ báǹkì àpapọ̀, CBN wí pé àwọn ń tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lójú mọ́lẹ̀ nù.

Emiefiele nínú ẹjọ́ tó pè tako DSS àti ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè látọwọ́ agbẹjọ́rò rẹ̀, J. B. Daudu ní DSS fi òun sí àhámọ́ lọ́nà àìtọ́.

Ó ní wọn kò fún òun ní ààyè láti rí àwọn ẹbí àti àwọn agbẹjọ́rò òun.

Àmọ́ níbi ìgbẹ́jọ́ náà tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, DSS ní tí ilé ẹjọ́ bá gba béèlì Emefiele, ó máa sá kúrò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni.
Agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà náà kín DSS lẹ́yìn nígbà tó ń júwe Emefiele bí ẹni tó le sá kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n bá ti tu sílẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn kò tẹ ẹ̀tọ́ Emefiele lójú mọ́lẹ̀ pẹ̀lú bó ṣe wà ní àhámọ́ àwọn nítorí ẹ̀mí rẹ̀ kò sí nínú ewu kankan.

Wọ́n ní àwọn kò fi ìyà jẹ ẹ́ tàbí ṣe é báṣubáṣu ní àgọ́ àwọn tó wà àti pé àwọn gba àṣẹ láti ilé ẹjọ́ kí àwọn tó fi òfin gbé e.

Wọ́n fi kun pé èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ò tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lójú mọ́lẹ̀ rárá nítorí àṣẹ ilé ẹjọ́ ni àwọn ń tẹ̀lé.

Nínú àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n jiyàn rẹ̀ pé kò sí nǹkan tó jọ mọ́ ṣíṣe agbátẹrù àwọn agbéṣùmọ̀mí lára ẹ̀sùn tí Emefiele ń kojú àti pé kìí ṣe wí pé nítorí pé ó dá sí òṣèlú tàbí ṣe àyípadà owó náírà sí owó tuntun ló ṣe okùnfà rẹ̀ gbígbé rẹ̀.

Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀sùn tí Emefiele ń kojú dá lórí ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ, dída ètò ọrọ̀ ajé ìlú rú àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn tó fara pẹ.

Agbẹjẹ́rò ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà, Tijani Gazal rọ ilé ẹjọ́ láti da ẹjọ́ tí Emefiele pè nù nítorí àwọn ẹ̀sùn náà kò rí ẹsẹ̀ walẹ̀.

Gazal tún ní ilé ẹjọ́ tí Emefiele gbé ẹjọ́ náà lọ kò ní àṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́ ọ̀hún.

Lẹ́yìn atótónu láti ẹnu àwọn agbẹjọ́rò, adájọ́ Hamza Muazu tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Keje láti gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here