Tinubu yọ alága EFCC, Abdulrasheed Bawa nípò

Tinubu yọ alága EFCC, Abdulrasheed Bawa nípò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fọwọ́ òsì júwe ilé fún ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn EFCC, Abdulrasheed Bawa.

Tinubu ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé fún àìní gbèdéke ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ààrẹ ní nítorí à ti fún àwọn tó ń ṣe ìwádìí Bawa láàyè láti ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ ni òun fi ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn lọ́kan-ò-jọ̀kan, èyí tó lágbára kan Bawa.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbenusọ akọ̀wé ìjọba orílẹ̀ èdè yìí, Willie Bassey ní Ààrẹ ní kí Bawa kó gbogbo àkóso àjọ náà lé adarí ètò gbogbo lọ́wọ́ títí tí wọ́n máa fi parí ìwádìí Bawa.
Abdulrasheed Bawa ni ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ tí wọ́n máa yàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà àjọ EFCC láti ìgbà tí wọ́n ti dá àjọ náà sílẹ̀ lọ́dún 2003.

Ọmọ ogójì ọdún ni Bawa wà nígbà tó fi máa gba ipò náà nínú oṣù Keje ọdún 2020 lẹ́yìn tí Ààrẹ àná, Muhammadu Buhari yọ Ibrahim Magu lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu.

Láti ọdún 2005 ni Bawa ti gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ́físà ní EFCC.

Òun ni ó ṣe ìwádìí ẹ̀sùn màkàrúrù owó tabua tí wọ́n fi kan Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fọ́rọ̀ epo rọ̀bì, Diezani Alison-Madueke.

Ìmọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, kó tó tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè fún ẹ̀kọ́ onípò kejì.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here